Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti gbe oriyin nla fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori iyansipo Onimọ-ẹrọ Sunday Adebayo Babalola gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ iṣakoso ajọ to n ri sọrọ epo rọbii, iyẹn Nigerian Upstream Petroleum Regulatory Commission (NUPRC).
AbdulRazaq ni ẹni ti wọn yan naa, to jẹ oloye ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC niluu Omu Aran jẹ alaṣeyọri to pe ye, to si ni oniruuru skọsilẹ nla gẹgẹ bii adari ati alaanu araalu.
O wa gbe oriyin fun Aarẹ Tinubu lori anfaani tumtun to fi bọwọ fun ipinlẹ Kwara, to si loun ni igbagbọ ati igboya wi pe yoo ṣe daadaa ninu iṣẹ ilu to gba.
No comments:
Post a Comment