Ijọba Kwara kede iwọle awọn akẹkọọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 4, 2026

Ijọba Kwara kede iwọle awọn akẹkọọ


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ki gbogbo ile-ẹkọ kaakiri ipinlẹ naa pada sẹnu eto ẹkọ fun saa ikẹkọọ keji lọjọ karun, oṣu Kinni, ọdun 2026.

Atẹjade ti Kọmiṣanna feto ẹkọ, Lawal Olohungbebe fi sita lọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2026 fidi rẹ mulẹ.

Ijọba Kwara ni awọn agbegbe ti eto aabo mẹhẹ, ṣugbọn ti agbekalẹ tuntun n lọ lọwọ ni ki wọn ṣi duro, titi digba ti eto yoo fi pari.

"A n ki awọn ọmọ wa pada sile ẹkọ kaakiri ipinlẹ yii. Ki gbogbo eto kikọ ati kika bẹrẹ loju ẹsẹ, ayafi awọn agbegbe ti a ti tọka si wi pe wọn nilo abojuto eto aabo to pe ye. Awọn ile-ẹkọ wọnyi la ni lerongba lati daabo bo awọn ọmọ wa kuro ninu ewu, nigba ti agbekalẹ tuntun n lọ lọwọ. Eto ẹkọ yoo bẹrẹ pada lawọn agbegbe naa laipẹ,' Kọmiṣanna sọ bẹẹ ninu atẹjade.

"Ni ifọwọsowọpọ pẹlu ajọ TESCOM ati SUBEB, ileeṣẹ yii n ki awọn ọmọ wa, olukọ ati obi ku oriire ọdun tuntun ati ilana eto ẹkọ to kun fun aṣeyọri."

Ileeṣẹ yii ti wa ṣagbekalẹ ilana eto ẹkọ ti ori redio, lati le jẹ ki eto ẹkọ gbooro si, kọja ti yara ikẹkọọ.

Olohungbebe sọ pe agbekalẹ naa yoo bẹrẹ lọjọ karun, oṣu Kinni, nipasẹ iranlọwọ ajọ UNICEF ati Nigeria Learning Passport, ni ibamu pẹlu afojusun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.

Atẹjade naa fi kun un pe awọn eto ori redio naa yoo waye nileeṣẹ redio Midland 99.1FM, bẹrẹ lati agogo mọkanla owurọ, laaarin ọjọ Aje si ọjọ Iṣẹgun; agogo kan ọsan ni Ọjọru; agogo meji aabọ ni gbogbo ọjọ Ẹti.

Bakan naa lo sọ pe wọn yoo ṣafikun awọn redio naa lọjọ iwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI