Lẹyin pade pẹlu awọn olori ijọ, Akewejẹ tun ṣepade pẹlu awọn agba Musulumi ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 4, 2026

Lẹyin pade pẹlu awọn olori ijọ, Akewejẹ tun ṣepade pẹlu awọn agba Musulumi ni Kwara


Lojuna lati jẹ ki iṣakoso Gomina 
Abdulrahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ṣe aṣeyọri lọdun 2026 ti a ṣẹṣẹ wọ yii, amugbalẹgbẹ gomina lori eto iroyin igbalode, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi ti ṣabẹwo sawọn olori ẹlẹsin Musulumi nipinlẹ naa.

Gbogbo awọn agba Musulumi ni wọọdu Ipetu/Rore ati Aran-Orin ni Akewejẹ ṣabẹwo si, to si rọ wọn lati gbadura fun iṣakoso to wa nita, fun aṣeyọri ati ilọsiwaju araalu.

Fafoluyi lo ṣe abẹwo ọhun lọjọ Ẹti, ọjọ keji, oṣu Kinni si awọn agba Imaamu ati Aafa.

“Iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fi ara jin fun iṣakoso rere ati irolagbara awọn igberiko fun idagbasoke nipasẹ agbekalẹ ti yoo mu ilọsiwaju ba gbogbo igberiko,” Akewejẹ sọ bẹẹ.

“Gẹgẹ bi ilu, awọn olori ẹlẹsin ni ojuṣe to pataki lati ṣe lati mu irori araalu bọ sipo fun iṣerere ijọba ati araalu. Idi ree ti mo fi maa n mọ riri awọn olori ẹlẹsin ti wọn mu ọrọ ipinlẹ ati orileede wa lọkunkundun ju ohunkohun to nii ṣe pẹlu ọrọ oṣelu lọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI