Ileeṣẹ Adron Homes fi imọriri han s'awọn onibara wọn kaakiri agbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 2, 2026

Ileeṣẹ Adron Homes fi imọriri han s'awọn onibara wọn kaakiri agbaye

Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes kaakiri agbaye, Aarẹ Adetola EmmanuelKing ti fi imọriri pataki han si gbogbo awọn onibara wọn kaakiri ilẹ Naijiria, ati awọn to wa loke okun.

Aarẹ EmmanuelKing ni oun ko le ṣai dupẹ lọwọ gbogbo awọn onibara ti wọn jẹ alatilẹyin ileeṣẹ wọn, pẹlu ileri wi pe awọn yoo tun tẹsiwaju ninu iṣẹ rere wọn.

Iduunu nla ni Aarẹ EmmanuelKing lo jẹ foun ati awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Adron Homes, pẹlu bi awọn onibara naa ṣe n polongo ọja wọn fun awọn onibara tuntun lọdun 2025 to kọja.

Nigba to n dupẹ ninu atẹjade to fi sita laipẹ yii, EmmanuelKing sọ ọ di mimọ pe igboya ati igbagbọ ti awọn onibara naa ni si ileeṣẹ wọn, lo jẹ igi lẹyin ọgba fun itẹsiwaju, idagbasoke ati bi wọn ṣe n ta kaakiri ilẹ Naijiria ati agbegbe rẹ.

“Lorukọ igbimọ iṣakoso, gbogbo mọlẹbi ẹgbẹ Adron, mo fi tọkantọkan dupẹ lọwọ awọn onibara wa nilẹ Naijiria ati loke okun fun igbagbọ ti wọn ni ninu afojusun wa ati bi wọn ṣe duro ti wa lọdun 2025. Igbagbọ, idowopọ ati bi ẹ ṣe n mu awọn eeyan wa lo n fun wa ni koriya lati tẹsiwaju,” Aarẹ EmmanuelKing sọ bẹẹ.

O ni gbogbo idokoowo ti awọn onibara ṣe yala ni ti ilẹ rira, dukia rira lo n ṣatọna ilọsiwaju wọn.

O wa sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa mu ọrọ awọn onibara lọkunkundun loorekoore lai ṣe ojusaaju lọdun 2026.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI