Ijọba ipinlẹ Kwara ti rọ gbogbo araalu lati wa ni ifura ati ikiyesara lasiko eto adura ipari ọdun wọnu ọdun tuntun.
Ijọba sọ pe ọpọ awọn oniṣẹ-ibi ni wọn yoo maa wa ipejọpọ rẹpẹtẹ lati fi ṣiṣẹ ibi ti wọn yan laayo.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto iroyin, Bolanle Olukoju fi sita, o ni awọn kan n gbero lati ba dukia ijọba jẹ kaakiri ipinlẹ naa.
"Ijọba Kwara rọ gbogbo araalu lati ṣọra, ki wọn si ma ṣe gba irin regberegbe laaye lagbegbe wọn, tabi ipejọpọ ti awọn ajinigbe yoo ti fẹẹ ṣọṣẹ," atẹjade naa sọ bẹẹ.
"Amọran yii ṣe pataki nitori olobo ti a ri gba lẹka eti iṣẹ aabo fi han pe awọn onigbagbọ buruku kan n gbero lati ba dukia ijọba jẹ, tabi igbesẹ miran pẹlu erongba lati gbẹsan adanu wọn.
"A gba awọn eeyan lamọran lati wa ni ikiyesara lasiko eto opin ọdun wọnu ọdun tuntun, ati ọlude ọdun tuntun, nigba ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo ba n ṣiṣẹ wọn lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu."
No comments:
Post a Comment