Ọkan lara awọn ọmọ aarẹ ilẹ Naijiria nigba kan ri, Ọjọgbọn Iyabọ Ọbasanjọ-Bello ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ogun.
Iyabọ Ọbasanjọ-Bello lo kede pe oun ti fi orukọ silẹ ninu eto iforukọsilẹ ẹgbẹ oṣelu APC to n lọ lọwọ kaakiri ilẹ Naijiria.
Wọọdu kọkanla to wa ni Ibogun, ijọba ibilẹ Ifọ ni obinrin naa to ti figba kan ri ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin agba Naijiria ti forukọsilẹ.
Nigba to n tu aṣiri naa fawọn akọroyin, alaga kansu nijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta nigba kan ri, Ọnarebu Biọdun Ajayi, ẹni to tun sunmọ Ọbasanjọ daadaa sọ pe Ọjọgbọn naa ti pari eto iforukọsilẹ tiẹ.
“Mo le fidi rẹ mulẹ pe Ọjọgbọn Iyabọ Ọbasanjọ-Bello ti pari eto iforukọsilẹ rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu wa lọjọ Iṣẹgun,” Ajayi sọ bẹẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC ko tii fidi rẹ mulẹ daadaa yala ninu atẹjade tabi ọrọ ẹnu, ṣugbọn sibẹ alakoso eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Nuberu sọ pe eto iforukọsilẹ to n lọ lọwọ naa faaye gba gbogbo ọmọ Naijiria lati darapọ, lati ọdun mejidinlogun lọ soke.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lọdun to kọja la mu iroyin naa wa pe patako alẹmode ipolongo obinrin naa wa kaakiri gbogbo ilu Abẹokuta ati agbegbe rẹ, leyi to mu ifura dani pe Ọbasanjọ n pada bọ lati du ipo nipinlẹ naa, iyẹn lọdun 2027.
Iyabọ Ọbasanjọ-Bello ti ṣe Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ogun laaarin ọdun 2003 si 2007, bẹẹ lo tun ti ṣe Sẹnetọ ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun laaarin ọdun 2007 si 2011.
No comments:
Post a Comment