Ọpọ awọn to wa nile ẹjọ giga tipinlẹ Ekiti to wa niluu Ado-Ekiti ni wọn pa ẹnu wọn silẹ nile ẹjọ, ti wọn ko si fẹẹ le pa a de, nigba ti ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun awọn mẹta kan.
Lasisi Afeez, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn; Ilesanmi Ṣeun, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Ajewọle Peter toun dagba ju laarin wọn , ẹni ọdun mẹtalelaadọta ni awọn mẹtẹẹta naa ti ile-ẹjọ dajọ iku fun.
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu igbimọ ọtẹ papọ, idigunjale ati lilo ibọn lọna aitọ ni ọlọpaa fi kan wọn niwaju Onidajọ Lekan Ogunmoye.
Awọn ẹsun naa lo tako abala 314, 312(2)(b) ati 344 ninu iwe ofin ọdaran nipinlẹ Ekiti, ti ọdun 2021.
Gẹgẹ bi ile-ẹjọ ṣe sọ ninu iwe idajọ, wọn ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022 ni awọn mẹtẹẹta lo ibọn ati ada lati ja ẹnikan to n jẹ Ojo Dada Emmanuel lole, ti wọn si gba ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla rẹ.
Yatọ si ọkọ ti wọn digun gba, wọn tun gba oruka igbeyawo, kaadi ATM, foonu, kọmputa alagbeeka meji ati ẹgbẹrun lọna aadọrin naira lọwọ Ojo.
Lọjọ naa ni wọn tun digun ja ẹlomiran to n jẹ Balogun Ahmẹd lole foonu meji ati ẹgbẹrun meji le ni igba (₦2,200) naira. Ibọn nla ẹlẹnu meji ni wọn ri lọwọ wọn lọjọ ti wọn jale yii.
Ọkan lara awọn ẹlẹri mẹta ti agbefọba pe lati jẹri tako awọn ọdaran naa, Emmanuel ṣalaye pe inu ile iwosan loun wa lalẹ ọjọ naa, toun si n palẹmọ lati ṣiṣẹ abẹ fun ẹnikan, ko to di pe wọn digun de.
Emmanuel jẹ ko di mimọ pe bi wọn ṣe wọle bi ologun igbajọba ni wọn ti yọ ibọn si wọn, ti wọn ni ki awọn doju bolẹ.
O ni alubami ni wọn lu oun pẹlu awọn alaisan, to fi mọ mọlẹbi alaisan lalẹ ọjọ naa, ti wọn si gba awọn dukia oun lọ, to fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ towo rẹ to miliọnu mẹta naira.
Siwaju sii lo ni oun gbọ pe wọn ti ta mọto oun naa ni gbanjo, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa rii gba pada foun.
Agbefọba Julius Ajibare, lẹyin to pe ẹlẹri mẹta lati jẹri, o tun ko awọn ẹri bii iwe ọkọ naa, ibọn kan, ọta ibọn ati awọn miran silẹ fun ile-ẹjọ.
Onidajọ Lekan Ogunmoye nigba toun n gbe idajọ kalẹ, jẹ ko di mimọ pe awọn ẹri toun ri gba fidi mulẹ, ko si ṣee fọwọ bo mọlẹ.
O wa paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun wọn titi ẹmi yoo fi bọ lara wọn.
No comments:
Post a Comment