Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi kan to ge ọwọ agbẹ kan lagbegbe Tede, ijọba ibilẹ Atisho, ipinlẹ naa, ti wọn si lawọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.
Ọlayinka Ayanlade to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kinni, ọdun 2026.
Ayanlade sọ pe afurasi naa, Sunday James lo ada lati ge ọrun ọwọ agbẹ naa, Benua Bukari nibi ti wọn ti n ja.
“Iwadii wa ṣafihan pe ẹnikan to n jẹ Benua Bukari, agbẹ to n gbe labule Ologede ni Tede lo ni aawọ pẹlu Sunday James, ti aawọ naa si di ija,” the statement read.
“Lasiko ija naa, niṣe ni Sunday James lọ fa ada yọ, to si fi ge ọwọ Benua Bukari.
“Lẹyin ti wọn fi to wa leti lawọn ọlọpaa lọ sibẹ lati wo ohun to ṣẹlẹ, ti wọn si fọwọ ṣikun ofin mu Sunday James, ẹni to wa lahaamọ wa nibi ti iwadii ti n lọ lọwọ.
“Bukari ti wa nile iwosan to ti n gba itọju lọwọ. Ija yii lo waye nitori aawọ to waye laaarin awọn ọmọbinrin mẹta kan to n gbe labule Ibudọ Kareem, Tede.”
Ileeṣẹ ọlọpaa wa ṣe ikilọ fawọn araalu lati dẹkun idajọ ọwọ ara ẹni.
.jpg)
No comments:
Post a Comment