Pakopako ni gendekunrin, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Ọlaitan Oloyede n wo lakolo ọlọpaa nigba ti aṣiri rẹ tu lori ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹjọ to ja ibale rẹ.
Agbegbe Oke Alaro to wa niluu Ibadan, ipinẹ Ọyọ ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, iyẹn nibi ti Oloyede n gbe.
Inu ile kan naa ni wọn sọ pe Oloyede ati awọn obi ọmọ naa n gbe, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ayanlade Ọlayinka fi sita laipẹ yii, o sọ pe iinu oṣu Kẹwaa,ọdun to kọja ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Ayanlade jẹ ko di mimọ pe ọmọ naa lo ṣalaye fun baba rẹ pe abẹ n dun oun, ati pe ẹnikan to n jẹ Oloyede lo fipa ba oun laṣepọ.
“Iwadii lo fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ọdun mẹjọ kan sọ fun baba rẹ pe oju abẹ n ta oun, ati pe alabagbe wọn, Ọlaitan Oloyede fipa ba oun laṣepọ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025,” atẹjade naa sọ bẹẹ.
Ayanlade ni loju ẹsẹ ni awọn ọlọpaa ti lọ sibẹ, ti wọn si fi ṣikun ofin mu afurasi naa
O ni awọn ọlọpaa lo mu ọmọ naa lọ sile iwosan fun ayẹwo ati itọju, to si tun fidi rẹ mulẹ pe ọmọ naa ṣi n gba itọju lọwọ.
Agbẹnusọ naa jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọwọ, ti ọmọkunrin naa si wa lahamọ awọn, sibẹ awọn yoo foju rẹ ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:
Post a Comment