Ọwọ ọlọpaa tẹ iya ati ọmọ to fẹẹ fọmọ ọdun mẹwaa ṣẹṣo l’Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 6, 2026

Ọwọ ọlọpaa tẹ iya ati ọmọ to fẹẹ fọmọ ọdun mẹwaa ṣẹṣo l’Ondo


Ṣikun lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo tẹ ọdaju abiyamọ kan pẹlu ọmọ rẹ ti wọn fẹẹ fi ọmọ ọdun mẹwaa ṣẹṣo owo.

Ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja yii ni ọlọpaa fi iroyin naa lede fawọn akọroyin niluu Akure.

Ninu atẹjade ti Abayomi Jimoh to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa fi sita, o ni ibi ti iya at'ọmọ naa ti fẹẹ fi ọmọ ọdun mẹwaa ọhun ṣoogun owo lọwọ ti tẹ wọn.

Jimoh darukọ iya gẹgẹ bi Maria, nigba ti ọmọ rẹ n jẹ Adewale.

O ni ilu Ile-Oluji to jẹ oluilu ijọba ibilẹ Ile-Oluji/Oke Igbo lọwọ ti tẹ wọn.

“Ileeṣẹ ọlọpaa tun ti ṣe akọsilẹ iṣẹ aṣeyọri ninu igbiyanju lati gbogun ti iwa ọdaran, pẹlu bi a ṣe rọwọ to afurasi meji kan ti wọn n gbiyanju lati ṣẹṣo ni Ile-Oluji lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2025,”

“Aṣeyọri yii lo waye pẹlu ẹka SWAT. Awọn ẹlẹyinju araalu ni wọn ta ọlọpaa lolobo, ti wọn fi tete gbera lọ sibẹ.

“Nibẹ lọwọ ti tẹ Maria, ẹni ọdun mẹtalelaadọta ati Adewle toun jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn; nigba ti a ri ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹwaa ti wọn n gbero lati lo gba silẹ ni alaafia. Ọmọ naa si ti wa nile iwosan fun itọju.”

O tẹsiwaju pe niṣe ni Maria ati ọmọ rẹ, Adewale lọ ba babalawo lan lati ba wọn ṣoogun owo.

Bẹẹ lo ni awọn mejeeji lo ti n ran ọlọpaa lọwọ láti ninu iwadii to n lọ lọwọ.

O wa fidi rẹ mulẹ pe awọn mejeeji ni yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI