Ẹrin keekee lẹnu awọn ara agbegbe Koko-Akojaga to wa niluu Ilaṣẹ, ijọba ibilẹ Ipokia nigba ti wọn ri gendekunrin ẹni ọdun mejilelogun kan tọwọ palaba rẹ segi nibi to ti n ta egboogi oloro ti n sunkun, to si n bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ.
Nnkan bi agogo mejila kọja iṣẹju mẹtadinlọgbọn, Ọjọru, Wẹside to kọja yii lọwọ tẹ ọmọkunrin naa Azeez Amuzat Ogo-Oluwa, ẹni ti wọn ni ko niṣẹ meji ju tita egboogi oloro lọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọwọ ẹṣọ aabo So-Safe Corps nipinlẹ Ogun lo tẹ Azeez nibi to ti n lọ ta awọn egboogi oloro naa ti wọn tun n pe ni 'Cannabis'.
Ori ọkada ni Azeez wa nigba tọwọ palaba rẹ segi, to si fẹẹ na papa bora nigba to rii pe aṣiri oun ti tu, ṣugbọn ti wọn ko jẹ ko raaye salọ.
Agbẹnusọ ẹṣọ aabo So-Safe Corps, Ọgbẹni Adegunwa Adegbuyi nigba to n ṣalaye fun AWIKONKO lalẹ Ọjọbọ to kọja yii, o sọ pe awọn oṣiṣẹ wọn to n gbogun ti fayawọ ohun ija oloro lo rọwọ to Azeez.
O ni lori igbesẹ lati tẹle aṣẹ ọga awọn, Sọji Ganzallo lati gbogun ti iwa ọdaran, lo mu ki alakoso ẹka to n ri igbogun ti ohun ija oloro, Abdulkareem Abdulrazak lo sọ fawọn ikọ rẹ lati jade ṣiṣẹ lọ.
Adegbuyi ṣalaye pe nibi ti wọn ti n lọ, ni wọn ti kofiri Azeez lori ọkada pẹlu baagi, ti iṣesi rẹ si mu ifura dani., idi ree to ni wọn ti daa duro lati yẹ baagi rẹ wo.
O ni loju ẹsẹ nibẹ ni Azeez ti bu sẹkun, to si n bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, ati pe oun yoo fiṣẹ naa silẹ lati gbajumọ iṣẹ kafinta toun kọ laaarọ ọjọ oun.
Agbẹnusọ naa wa jẹ ko di mimọ pe lẹyin t'awọn f'ọrọ wa a lẹnu wo tan, ni ọga awọn, Ganzallo paṣẹ pe ki wọn lọ fa a le ajọ to n gbogun ti egboogi oloro, iyẹn NDLEA, ẹkun Idiroko lọwọ lati tẹsiwaju iwadii.
Ganzallo nigba to n gba araalu lamọran lati yago fun egboogi oloro, o ni bo ṣe n ṣakoba fun agọ ara, naa lo tun jẹ iwa ọdaran lorileede Naijiria.
O wa sọ pe ẹni tọwọ ba tẹ pẹlu eyikeyi egboogi oloro, yoo foju winna ofin lẹyin t'awọn ba fa a le awọn ileeṣẹ tabi ajọ tọrọ naa ba kan lọwọ.
No comments:
Post a Comment