Ileeṣẹ China nla meji ni wọn ti n gbaradi lati bẹrẹ iṣẹ bayii nipinlẹ Kwara, leyi ti yoo mu anfaani igbanisiṣẹ dide fun awọn ọdọ.
Miliọnu marundinlogoji ọwọ dọla ni wọn fẹẹ fi da awọn ileeṣẹ naa silẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Nigba to n sọrọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita, lẹyin ipade pẹlu awọn alakoso ile-iṣẹ naa, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe lara awọn akitiyan iṣakoso rẹ lo n mu ki awọn ileeṣẹ nalnla lagbaye wọle si Kwara.
O ni awọn ileeṣẹ naa yoo tun mu ki eto ọrọ aje ipinlẹ Kwara tẹsiwaju, pẹlu bo ṣe di ipinlẹ apewaawo fun awọn eeyan lagbaye.
Sun Qing Rong, to ṣoju ikọ ileeṣẹ ER-KANG Company Limited, sọ pe igbesẹ awọn ti pari lati bẹrẹ ileeṣẹ ti yoo maa ṣe awọn ohun ti wọn n pe ni litiọmu (lithium), eyi ti ọwọ ti wọn fẹẹ fi bẹrẹ ko din ni ogun miliọnu owo dọla.
O sọ pe awọn fẹẹ bẹrẹ ileeṣẹ naa no ibamu pẹlu agbekalẹ ilana ijọba Kwara, leyi ti yoo mu imugbooro ba eto ọrọ aje, ati anfaani araalu.
Rong sọ pe oṣiṣẹ ti ko din ni ọọdunrun to jẹ ọmọ bibi ati olugbe ipinlẹ Kwara lawọn ti gba si iṣẹ ni ileeṣẹ wọn, lati mu adinku ba airiṣẹṣe.
No comments:
Post a Comment