Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ki eto ẹkọ bẹrẹ pada ni pẹrẹu lawọn ile-ẹkọ to wa ni titipa lati ọdun to kọja.
Atẹjade ti Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọmọwe Lawal Olohungbebe buwọlu, ni akọwe iroyin rẹ, Peter Amogbonjaye fi sita lọjọ Aiku ana lo fidi rẹ mulẹ.
Kọmiṣanna sọ pe ki awọn ile-ẹkọ naa bẹrẹ eto ẹkọ lakọtun, bẹrẹ lati oni, ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu keji, ọdun 2026.
O ni lẹyin ti gbogbo eto ti to pada lẹka eto aabo, to si ni awọn oṣiṣẹ eleto ti gbajọba lọwọ awọn agbesunmọmi aṣekupani, ki ohun gbogbo pada bọ sipo.
Siwaju sii lo ṣalaye pe gbogbo awọn alakoso ile-ẹkọ lawọn agbegbe ti eto ẹkọ ti koju ipenija ni wọn ti kan si pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn.
No comments:
Post a Comment