Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ipinlẹ Ogun naa wa lara awọn ipinlẹ ti wọn da silẹ lọdun 1976, ti wọn si n ṣayẹyẹ idasilẹ aadọta ọdun wọn bayii.
Bi awọn ipinlẹ yooku ti wọn n ba yọ, ipinlẹ ọhun ko gbẹyin ninu awọn ipinlẹ to ti ni idagbasoke alailẹgbẹ, ti wọn si n ba yọ.
Lara awọn to n ki wọn ku oriire ni alaga igbimọ iṣakoso ileeṣẹ ati gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ Adron Group patapata.
Aarẹ Adetola EmmanuelKing gbe oriyin nla fun Gomina Dapọ Abiọdun lori awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n mu ki ipinlẹ naa tẹsiwaju ni oriṣiriṣi ẹka.
"Alaga, igbimọ iṣakoso, awọn alakoso ati oṣiṣẹ ileeṣẹ Adron Group n ki ijọba ati gbogbo ara ipinlẹ Ogun ku ayẹyẹ idasilẹ aadọta ọdun," atẹjade ti wọn fi sita sọ bẹẹ.
Wọn ni awọn ohun to n ṣẹlẹ lasiko yii jẹ idaniloju iṣakoso rere, ati ipo adari to ni afojusun ati erongba rere fun idagbasoke ọjọ iwaju.
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe "latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ondo silẹ lọdun 1976, ipinlẹ naa ti da ara rẹ yatọ lati jẹ aarin gbungbun fun ibọwọfun, ọgbọn inu ati okoowo.
"Gẹgẹ bi wọn ti n pe wọn ni ipinlẹ itanṣan oorun, ipinlẹ naa ti pese awọn iran awọn ọjọgbọn, alakoso ati adari apapọ to jẹ pe ipa wọn ko kere ninu idagbasoke ati itẹsiwaju ilẹ Naijiria yala lẹka eto ọrọ aje ni tabi idagbasoke oṣelu."
Wọn wa gbe oriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun lori awọn akitiyan rẹ lati mu ipinlẹ naa le tente laaarin awọn akẹgbẹ rẹ nipa idagbasoke ni oniruuru ẹka.
No comments:
Post a Comment