Lojuna lati jẹ ki gbogbo oṣiṣẹ ijọba kopa daadaa ninu ayẹyẹ ọdun Itunu Aawẹ Ramadaani to wa nita lasiko yii, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bẹrẹ sisan owo oṣu Kẹta fun gbogbo awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Kwara.
Eyi yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ra awọn ohun ti wọn nilo lati fi ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun Itunu Aawẹ Ramadaani naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, kii ṣe igba akọkọ ree ti Gomina AbdulRazaq yoo maa san owo oṣu awọn oṣiṣẹ lasiko ti ayẹyẹ ọdun bayii ba wọle de, gẹgẹ bi ifẹ to ni si awọn araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ lapapọ.
No comments:
Post a Comment