Ajalu nla lo tun wọnu agboole olorin ilẹ Naijiria nni, nigba ti iroyin jade sita pe Taiwo, ọkan lara ibeji Adegbodu ti jade laye.
Taiwo Adegbodu ni wọn kede iku rẹ laaarọ ọjọ Aiku, ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2026.
Oju opo ayelujara awọn ibeji naa ti wọn ti kede iroyin iku Taiwo Adegbodu.
“Taiwo, ki lo de ti o fi emi ati awọn ọmọ rẹ silẹ lai dagbere? Ọkan mi n ṣẹjẹ, Ọlọrun, ba wo lo ṣe fẹ ki n maa lo igbesi aye mi lai si Taiwo? Ki lo de Ọlọrun? Eleyi pọ ju fun mi lati gba mọra!”, atẹjade naa ka bẹẹ.
Bakan naa ni gbajugbaja olorin nni, Esther Igbekele tun kede iroyin iku taiwo Adegbodu loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku.
Igbekele ninu aworan to fi sita, lo kọ apele sabẹ rẹ pe, “Erin wo, Ajanaku sun bi oke. O le lati gba. O daarọ, arakunrin.”
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii mọ iru iku to pa Taiwo Adegbodu, sibẹ, awọn ololufẹ wọn kaakiri agbaye ti bẹrẹ sii fi atẹjiṣẹ ibanikẹdun ranṣẹ si wọn.
Ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ ni Taiwo ati Kehinde Adegbodu, ti wọn si di olokiki lẹyin ti wọn gbe awọ orin “Faratimi (Lean on Me)” to gba gbogbo igboro jade lọdun 1999.
Ọpọ orin bii “Shower Your Blessing”, “God Concert”, “Emi Mimo”, “Igbagbo Dun”, “Ma Beru” ati “Adura Mi Gba”, to fi mọ awọn orin miran ni awọn mejeeji ti gbe jade, koda ti wọn tun n lọ kaakiri lati kọrin f'awọn eeyan.
Ipa ti wọn ko lawujọ olorin nilẹ Naijiria, lo jẹ ki Gomina Ademola Adeleke tipinlẹ Ọṣun fi wọn hẹ oludamọran pataki lori eto amuludun ati irin ajo afẹ nipinlẹ naa.

No comments:
Post a Comment