Awa ko fọwọ si afikun owo tikẹẹti ni Kwara o - Ijọba pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 27, 2026

Awa ko fọwọ si afikun owo tikẹẹti ni Kwara o - Ijọba pariwo sita


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe eto igbayegbadun awọn araalu, paapaa awọn awakọ lo jẹ ohun logun, ati pe ni gbogbo igba lohun yoo maa wa gbogbo ọna lati jẹ ki wọn jẹ igbadun aye wọn.

Ana, Ọjọbọ ni Kọmiṣanfeto igbokegbodo ọkọ, Lafia Aliyu Korasabi sọrọ naa nibi ipade to ṣe pẹlu awọn oloye ẹgbẹ oni Maruwa, iyẹn Tricycle Owners Association of Nigeria (TOAN).

Ipade naa ko ṣẹyin b'awọn oni Maruwa ṣe fẹhonu han nipa owo ori ti awọn agbero n gba, eyi to kọja agbara wọn.

Ọnarebu Lafia, sọ pe owo tikẹẹti ti ijọba n gba lọwọ awọn awakọ ati oni maruwa jẹ ajọsọ ti wọn fẹnu ko le lori nipa ifẹ ati igbayegbadun awọn alẹnulọrọ.

O sọ pe pẹlu gbogbo owo tikẹẹti ti awọn araalu n ja lori ọkọ, ọkada ati maruwa, igba naira pere lo n lọ sapo ijọba lati ileeṣẹ to n ri sọrọ ipawo-wọle nipinlẹ naa, Kwara State Internal Revenue Service (KWIRS).

Lafia sọ pe ijọba ko lọwọ si eyikeyi awuyewuye to n lọ nipa afikun owo owo, to si ni ki wọn da owo tikẹẹti naa pada si ẹẹdẹgbẹrin naira ti wọn fẹnu ko le lori tẹlẹ.

O jẹ ko di mimọ pe iṣakoso AbdulRazaq mu ọrọ igbayegbadun araalu, paapaa awọn awakọ lokunkundun.

“Ijọba fẹ ki gbogbo awọn tọrọ naa kan tẹle ilana ati aṣẹ, ki wọn si gba ofin laaye, ẹnikẹni tọwọ ba tẹ, to tapa si ilana to wa nilẹ yoo foju winna ofin. A rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn olori nidi iṣẹ igbokegbodo ọkọ lati ko ara wọn nijanu, ki wọn si gba ifẹ ati alaafia laaye,” Kọmiṣanna sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI