Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni Akewejẹ tiluu Aran-Orin nijọba ibilẹ Irepodun, Oloye Olayinka Fafoluyi ṣabẹwo s'awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ilu Ipetu, Rore ato Aran-Orin, lati fi erongba rẹ han lori ipo aṣofin sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara.
Fafoluyi jẹ ko di mimọ ni awọn wọọdu naa oun fẹẹ jade du ipo aṣofin lati ṣoju wọn nile igbimọ aṣofin ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ lọna.
Ọkunrin naa to tun jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode rọ awọn alẹnulọrọ naa lati dide iranwọ foun lasiko eto idibo abẹle to n bọ ninu oṣu karun-un.
Fafoluyi ṣeleri pe oun yoo ṣoju wọn daadaa nigba ti wọn ba ṣe atilẹyin foun ninu idije naa.
No comments:
Post a Comment