Akewejẹ Fafoluyi tu aṣiri idi to fi fẹẹ du ipo ile igbimọ aṣofin ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 1, 2026

Akewejẹ Fafoluyi tu aṣiri idi to fi fẹẹ du ipo ile igbimọ aṣofin ni Kwara


Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Kwara, Oloye Olayinka Fafoluyi ti fi erongba rẹ han lati jade du ipo gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin ti yoo ṣoju awọn ara agbegbe Aran-Orin nijọba ibilẹ Irepodun.

"Mo ki ẹyin baba mi, ẹyin iya mi, ẹyin agbaagba, ẹyin ọdọ, ẹyin agbaagba ẹgbẹ, ẹyin alẹnulọrọ, ati ẹyin eeyan rere ni ẹkun idibo Irepodun. Mo ki gbogbo yin patapata," eyi ni Akewejẹ Fafoluyi fi bẹrẹ ọrọ rẹ.

Ọjọbọ to kọja yii ni Fafoluyi ṣepade abẹle pẹlu gbogbo awọn alẹnulọrọ ati araalu patapata nijọba ibilẹ Irepodun, nibi to ti lọ fi erongba han fun ipo aṣofin, to si n bẹbẹ fun atilẹyin wọn lasiko eto idibo ọdun 2027.

"Mo fẹẹ dupẹ lọwọ awọn adari ẹgbẹ wa, All Progressives Congress (APC), fun ifarajin wọn ninu idagbasoke ati iṣọkan. Mo mọ riri alaga ẹgbẹ oṣelu APC wa ati awọn oloye ẹgbẹ, nipa bi wọn ṣe fi tẹriba fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, eyi jẹ apẹẹrẹ rere fun ipo adari.

"Oni kii ṣe ikorajọ lasan. O jẹ apẹẹrẹ rere, ifarajin ati igbesẹ."

Fafoluyi sọ pe idunnu nla lo jẹ foun lati wa niwaju awọn agbaagba ati awọn alẹnulọrọ ilu Aran-Orin, pẹlu atilẹyin ti wọn fi han s'oun.

"Tọkantọkan nipa ojuṣe ati itẹriba si Ọlọrun ati ẹyin eeyan mi, emi, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi, tọpọ tun mọ si Solace, wa jẹ ko di mimọ fun un yin nipa erongba mi lati lati ṣoju yin, ẹyin eeyan rere ni agbegbe Irepodun, nile igbimọ aṣofin aṣofin ipinlẹ Kwara.

"Ipinnu yii kii ṣe nipa erongba mi nikan, bi ko ṣe nipa wi pe awọn eeyan Irepodun nilo ohun to dara ju bayii lọ."

O wa sọ pe awọn iriri oun gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori eto iroyin igbalode, ti ṣi oju oun si iṣakoso, biba awọn araalu sọrọ, ati ojuṣe lati ṣe ohun tawọn eeyan nilo lasiko to yẹ. "Mo ti kẹkọọ wi pe ipo adari gidi kii ṣe nipa ọrọ ẹnu nikan, bi ko ṣe nipa esi."

O loun ti ri awọn kudiẹkudiẹ to wa laaarin awọn agbegbe toun fẹẹ lọ ṣoju, to si ṣeleri pe oun yoo ṣoju wọn de ibi to ni apẹẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI