Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fidi rẹ mulẹ pe afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ko din ni mẹtalelogun ni wọn ti wa lahaamọ awọn, nibi ti wọn ti n ṣe iwadii wọn lọwọ.
Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita jẹ ko di mimọ pe ibọn marun ọtọọtọ ni wọn gba lọwọ awọn afurasi naa, lasiko ti wọn lọ ka wọn mọ buba wọn, kaakiri agbegbe to wa nipinlẹ Eko.
Ọlọpaa sọ pe awọn agbegbe bii Ikorodu, Lagos Island, Okoko, Ilasan, Ọgba ati Iju ni awọn ti ṣiṣẹ lati kọju awọn ọdaran, ninu igbesẹ lati f'ofinn si iwa ẹgbẹ okunkun, iwa ipa ati lilo ibọn lọna aitọ.
A gbọ pe olobo to tẹ ọlọpaa lọwọ lo jẹ ki wọn dide lati ṣiṣẹ iwadii, ko to di pe ọwọ palaba awọna afurasi naa segi.
"Mẹrin lawọn tọwọ tẹ niluu Ikorodu lori iwa ṣiṣe ẹgbẹ okunkun," ọlọpaa sọ bẹẹ, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ iwadii ni wọn fi tọpinpin wọn de inu ẹgbẹ Buccaneer ti wọn tun n pe ni Sea Lords.
Wọn sọ siwaju pe afurasi mẹsan lọwọ tẹ lagbegbe Lagos Island; marun-un lọwọ tẹ lagbegbe Ilasan lori ẹsun pipa ẹnikan to n jẹ Emmanuel Obioson.
Siwaju sii, ọlọpaa sọ pe afurasi kan ti wọn nigbagbọ pe inu ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ loun wa, ni wọn tọpinpin de agbegbe Okoko, tọwọ si tẹ ẹ pẹlu ibọn kan.
Awọn mẹrin yooku ni wọn lọwọ tẹ lagbegbe Ọgba ati Iju, ti wọn si gba ibọn ati nnkan ija oloro lọwọ wọn.
“Shina Wale, ẹni ọdun mẹrindinlogoji; Kehinde Kareem, ọmọ ọdun mejidinlogun; Mohammed Aileru, ọmọ ọdun mejidinlogun; Bada Mujeeb, ọmọ ọdun mejidinlogun; Salam Kosoko, ọmọ ọgbọn ọdun; Yusuf Anjorin, ọmọ ọdun mọkandinlogun; Quadri Abubakar, ọmọ ọdun mọkanlelogun; Lateef Salako, ọmọ ọdun mejidinlogun; Fawaz Bello, ọmọ ọgbọn ọdun; Oyesola Olalekan, ọmọ ọdun mẹrindinlogoji; Ubaka Justice, ọmọ ọdun mẹrindinlogoji; Emmanuel Obekpa,ọmọ ọdun mẹrindinlogoji; Sodiq Ademola, ọmọ ọdun mẹrindinlogoji; Balogun Taofeek, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn; Azeez Owolabi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Meshack Obini, ẹni ọdun mẹrinlelogun; Fabulous John, ẹni ọdun marundinlọgbọn; Promise Israel, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Bright Aniedi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn; Familola Fikayo David, ẹni ọdun mẹrinlelogun; Akeem Olamilekan, ẹni ọdun mẹtalelogoji; Muiz Oyedele, ọmọ ogun ọdun; ati Hamzat Sadiq toun jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun.
Ọlọpaa ti wa sọ pe lẹyin iwadii, gbogbo wọn yoo foju ba ile-ẹjọ.

No comments:
Post a Comment