Ìtàn tí o lè gbẹ́kẹ̀lé: Àwọn àbájáde iṣẹ́ àkànṣe Ọ́nárébù Ọlúsùmbọ̀ Florence Oyẹ̀yẹmí lẹ́ka ètò ìlera (Apá Kẹrìn) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 16, 2026

Ìtàn tí o lè gbẹ́kẹ̀lé: Àwọn àbájáde iṣẹ́ àkànṣe Ọ́nárébù Ọlúsùmbọ̀ Florence Oyẹ̀yẹmí lẹ́ka ètò ìlera (Apá Kẹrìn)


Odu ni gbajugbaja Ọnarebu nni, Arabinrin Olasumbo Florence Oyeyemi kaakiri ipinlẹ Kwara ati agbegbe rẹ, paapaa nilẹ Naijiria, kii ṣe aimọ fun oloko.

Ọnarebu Oyeyemi ẹkun idibo Ekiti/Irepodun, Isin/Oke-Ero nile igbimọ aṣojuṣofin ilẹ Naijiria, eyi to wa ni Abuja.

Akikanju obinrin naa ni lo ti ko ipa to jọju ninu idagbasoke ati ilọsiwaju awọn agbegbe to n ṣoju.

WO AWỌN OHUN TO TI ṢẸLẸ NIPA IRANLỌWỌ ETO ILERA

Ni ohun to kọja eto ọrọ aje awọn obinrin ati irolagbara eto ẹkọ awọn ọdọ, Ọnarebu Olasumbo Florence Oyeyemi tun ni igbagbọ wi pe agbegbe to ni ilera pipe jẹ eyi to ni ọrọ rẹpẹtẹ.

Ninu awọn akitiyan rẹ lo tun gbooro siwaju si ẹka eto ilera ati igbayegbadun awọn eeyan.

Nipa ipolonogo eto yii, Ọnarebu Oyeyemi ti ṣe iranlọwọ to pọ, lati rii pe awọn araalu ni anfaani si eto ilera, paapaa awọn eeyan to wa lawọn agbegbe to n ṣoju.

Ni afikun, o tun ti ṣe iranlọwọ atigbadegba fun awọn eeyan to nilo iranwọ, nipa dide lasiko to yẹ, eyi to ti mu irọrun ba igbe aye awọn eeyan ati mọlẹbi lapapọ.

Awọn igbesẹ yii lo ṣafihan adari ti kii ṣe pe o ṣagbekalẹ awọn eto nikan, bi ko ṣe pe o yun n dide iranlọwọ fun awọn alaini to nilo aanu.

Yèyélúà, gẹgẹ bi wọn tun ṣe maa n pe e, lo fi ara jin fuj itẹsiwaju eto yii lati gbooro sii, nipa anfaani si eto ilera, paapaa julọ, awọn to nilo iranlọwọ pajawiri bii awọn alaboyun ati awọn ọmọde, nipa agbekalẹ eto ti wọn pe ni "Mother and Child Care Initiative", lati rii pe awọn agbalagba ri itọju to peye kaakiri awọn agbegbe to wa lẹkun Ekiti/Irepodun ati Isin/Oke-Ero. Federal Constituency.

Ọnarebu Oyeyemi ti n kopa to jọju nigbesi awọn araalu, to si tun ṣetan lati ṣe sii.

Lati Ọdọ Awọn: YÈYÉLÚÀ MEDIA BRAINBOX

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI