Awọn ẹgbẹ alatako nilẹ Naijiria ti ṣeleri pe awọn ti ṣetan lati gba ipo lọwọ Aarẹ bola Ahmed Tinubu ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ lọna.
Nibi ipade awọn alẹnulọrọ kaakiri ẹgbẹ alatako to waye niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo laipẹ yii ni wọn ti fẹnuko.
Nibẹ ni wọn tun ti pe fun ifipo silẹ ỌJọgbọn Joash Amupitan gẹgẹ bi alaga ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, iyẹn INEC, ṣaaju eto idibo ọdun 2027 naa.
Bakan naa lawọn miran tun rọ ile igbimọ aṣofin agba lati ṣagbeyẹwo ofin eto idibo ọdun 2026, ati titu awọn agba oloṣelu to wa lahaamọ silẹ, to fi mọ sisun eto idibo abẹle awọn ẹgbẹ oṣelu siwaju.
Ninu abajade ipade naa to waye lọjọ Abamẹta, eyi ti wọn fi sita, wọn ni awọn ko le tẹwọ gba ojusaaju ti Amupitan fi n dari ajọ INEC, lati fi ṣe ojurere fun ẹgbẹ oṣelu APC.
Wọn lawọn ko le gba ki Amupitan ṣe akoso eto idibo ọdun 2027, pẹlu bo ṣe wa lẹyin ẹgbẹ oṣelu APC, to si ti fi han daju pe ẹgbẹ APC lo n ṣiṣẹ fun, eyi ti wọn sọ pe ko boju mu to.

No comments:
Post a Comment