Gomina Abiọdun fa ọwọ Sẹnetọ Yayi soke gẹgẹ bi omo oye s’ipo gomina l’Ogun
Lọjọ Aje, ọsẹ yii, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ni Gomina Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun ti kede Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Guusu Iwọ-Oorun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin agba ilẹ Naijiria, Sẹnetọ Solomon Olamilekan Adeola gẹgẹ bi ẹni ti ẹgbẹ bi oludije sipo gomina ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC fa kalẹ alti dije fun ipo gomina l’Ogun ninu eto idibo ọdun 2027.
Gomina Abiodun kede Sẹnetọ Adeola tọpọ awọn eeyan tun n pe ni Yayi nibi ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ naa to waye niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ naa.
Nigba to n sọrọ, gomina sọ pe ẹni ti ọkan gbogbo ọmọ ẹgbẹ yan lati gbe ọpa aṣẹ ipinlẹ naa le lọwọ ni Sẹnetọ Yayi, ẹni to ti ko ipa ribiribi ninu idagbasoke ipinlẹ naa.
Gomina naa sọ pe kii ṣe pe oun da ipinnu naa ṣe, bi ko ṣe pe lẹyin ijiroro laaarin awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ẹgbẹ lo fẹnu ko lori Sẹnetọ Yayi.
“Igbesẹ naa lo ṣafihan ajọsọ gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ nipinlẹ yii, Sẹnetọ Adeola yẹ lati gbe asia ẹgbẹ lọdun 2027,” Gomina Abiọdun sọ bẹẹ.
O wa jẹ ko di mimọ pe oun nigbagbọ to jinlẹ wi pe eto gbigbe ipo silẹ yoo lọ bo ti tọ, ati bo ti yẹ nipa iwuri f’oun, nitori pe inu ẹgbẹ naa ni ẹni ti yoo jawe olubori ti jade.
"Lati fi ẹnu ko lori oludije kan ṣoṣo yii, a ti jẹ ko ye awọn oludije yooku ni ẹkun Guusu Iwọ-Oorun lati jẹ ki oye ye wọn, awọn bii Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka ati Ọnarebu Isiaq Abiodun Akinlade, ti wọn si ti fi ifẹ ati iṣọkan han nipa ifẹ agbegbe wọn ati ẹgbẹ.
"Pẹlu apapọ, la fi n fọ gbogbo ohun to n dena ẹkun naa lati rii pe wọn fa gomina kalẹ ni ipinlẹ wa.
"A kan si awọn eeyan, awọn agbaagba ati alẹnulọrọ kaakiri lati rii pe wọn fa oludije to kaju oṣuwọn kalẹ, leyi ti erongba rẹ yoo ba afojusun rere fun ipinlẹ Ogun wa mu.
"Erongba wa ko duro lori amuyẹ yii nikan, ṣugbọn o tun pin ninu ifarajin lati rii pe itẹsiwaju ti a ti n ṣe lati ọdun pipẹ sẹyin tẹsiwaju.
"Gẹgẹ bii ẹgbẹ, a ma maa dagba ninu okun sii, ti a si maa wa ni iṣọkan lati gbe ipinlẹ Ogun lọ si ipele miran ninu idagbasoke," Gomina Abiodun sọ bẹẹ.
O wa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati tubọ ni afojusun, ki wọn si maa tẹle ofin, ati ki wọn duro lori afojusun apapọ ọmọ ẹgbẹ, bi eto idibo gomina ṣe n sunmọ etile.
Bẹẹ lo sọ pe pẹlu asia ti wọn gbe le Sẹnetọ Adeola lọwọ yii, oun nigbagbọ pe yoo duro lori ilana idagbasoke ti yoo ṣafihan eto oṣelu awa-ara-wa, ni ibamu pẹlu afojusun awọn araalu.
Fun awọn ti ko ba mọ, lati bii ọdun mẹsan sẹyin ni Sẹnetọ Yayi ti ni erongba lati jade du ipo gomina nipinlẹ Ogun, paapaa nigba to ṣi n ṣoju awọn ara agbegbe kan nipinlẹ Ekoo nile igbimọ aṣofin agba naa.

No comments:
Post a Comment