Ọbasanjọ tu aṣiri idi ti ileeṣẹ ifọpo ilẹ Naijiria ko ṣe le ṣiṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 27, 2026

Ọbasanjọ tu aṣiri idi ti ileeṣẹ ifọpo ilẹ Naijiria ko ṣe le ṣiṣẹ

Aarẹ tẹlẹri nilẹ Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti tu awọn aṣiri tuntun nipa bi ileeṣẹ ifọpo aladani tilẹ Naijiria ko ṣe le ṣiṣẹ.

Ọbasanjọ sọ pe pẹlu bi ijọba apapọ ṣe n sa ipa ati akitiyan lati rii pe ileeṣẹ ifọpo naa pada ṣiṣẹ, o ni bi ẹni to n yin agbado sẹyin igba ni, nitori pe ilakaka naa ko le so eso rere.

Agba oloṣelu naa lo sọ eyi ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lalẹ ọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja yii.

Aarẹ tẹlẹri lo sọrọ naa, lasiko ti ileeṣẹ to n ri sọrọ epo rọbii nilẹ Naijiria, Nigerian National Petroleum Company Limited gbiyanju lati wa awọn alafọwọsowọpọ ti yoo maa ṣakoso ileeṣẹ ifọpo Port Harcourt, Warri ati ti Kaduna.

Nibẹ ni Ọbasanjọ ti jẹ ko di mimọ pe awọn iriri oun lati ẹyin wa, ti jẹ ko ye oun pe ijọba Naijiria yoo maa na owo lori okoowo kan, ti wọn ko si nii ṣe aṣeyọri, ṣugbọn to jẹ pe eyi to ba jẹ ti aladani ni yoo maa ṣe aṣeyọri.

“Ọkan lara awọn ẹkọ ti mo kọ ni pe ibaṣepọ pẹlu awọn aladani maa n ṣiṣẹ. Ewo, okoowo kan ṣoṣo ti ijọba Naijiria ko tii bajẹ ni ti afẹfẹ gaasi, iyẹn ‘Nigeria Liquefied Natural Gas’ (NLNG), nibi ti ijọba ti ni iṣakoso ida mọkandinlaadọta, ti awọn aladani si ni ida mọkanlelaadọta,” Ọbasanjọ sọ bẹẹ.

O jẹ ko di mimọ pe ọpọ igba ni igbesẹ ati akitiyan lati gbe ileeṣẹ ifọpo dide lori ti foriṣanpọn lati ọpọ ọdun sẹyin, koda lasiko toun wa ni iṣakoso gẹgẹ bi aarẹ, to si loun ti wa ri daju pe awọn dukia ijọba ko le ṣiṣẹ to ba ba ṣi wa labẹ iṣakoso ijọba.

O fi kun ọrọ rẹ pe, “Ẹ wo ohun ti a ṣe pẹlu ileeṣẹ reluwee. Ẹ wo ohun ti a ṣe ni ẹka kiko ẹru wọle. Ẹ wa wo ohun ti a n ṣe bayii, koda ni ẹka NNPC. NNPC ni ileeṣẹ ifọpo, mo si maa n sọ fawọn eeyan pe ko le ṣiṣẹ. Ẹnikan si wa n sọ pe ‘Ṣe mo jẹ onimọ-ẹrọ iṣẹ kẹmika?”

Ọbasanjọ tun fi kun ọrọ rẹ pe oun ti lọ ba ileeṣẹ Shell nigba kan lati gba iṣakoso ileeṣẹ ifọpo, ṣugbọn to ni awọn alakoso ileeṣẹ naa kọ jalẹ lọpọ igba.

“Nigba ti mo wa nibẹ, mo pe ileeṣẹ Shell, mo si bẹ wọn lati gba ida mẹwaa, ki wọn le maa ṣakoso ileeṣẹ ifọpo naa fun wa. Wọn sọ pe rara. MO beere nipa idi ti wọn ko fi fẹẹ gba iṣakoso, wọn wa jẹ ko ye mi nipa ibi ti wọn ti n ri ere rẹpẹtẹ.”

Bakan naa lo sọ pe oun ranti ti Aliko Dangote ṣe wa lati gba iṣakoso ileeṣẹ ifọpo meji, to si loun pada gbe lee lọwọ, ṣugbọn to tun jẹ iyalẹnu nigba ti NNPC tun gba awọn ileeṣẹ ifọpo naa pada lẹyin toun kuro nijọba.

O ni latigba naa ni nnkan ko ti lọ deedee, toun si mọ pe ko le si ọna abayọ, ayafi bi ijọba apapọ ba ṣe oun to yẹ, lasiko to yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI