Orin ọkan lara awọn olorin ilẹ Naijiria, iyẹn ni ẹkun Iwọ-Oorun, 'Mega 99', to kọ pe "ẹ maa jo o, ẹ maa yọ, Ọlọrun ti fi ayọ si aye wa, ẹ maa yọ", ni ọpọ awọn arugbo ati Opo mu sẹnu, nigba ti wọn gbọ pe Akewejẹ ilu Aran-Orin to wa nijọba ibilẹ Irepodun, ipinlẹ Kwara, Oloye Michael Olayinka Fafoluyi fẹẹ fi owo iranwọ da wọn lọla.
Awọn Opo ati arugbo ti ko din ni ọtalenigba, iyẹn 250 kaakiri ilu Ipetu, Rore ati Aran-Orin, nijọba Irepodun ni wọn fẹẹ jẹ anfaani owo iranwọ yii.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ iroyin Akewejẹ Fafoluyi tọpọ awọn eeyan tun mọ si Solace fi sita lọjọ Ẹti, Furaide, ni wọn ti sọ pe ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2026 ni eto ọhun yoo waye.
Ileeṣẹ iroyin naa fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹrun mẹwaa naira ni Opo kan ati arugbo kan yoo gba, gẹgẹ bi owo iranwọ.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Akewejẹ yoo maa ṣe iru iranwọ bayii fawọn araalu, latigba to ti wa nipo amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara, iyẹn ni saa akọkọ lo ti n ṣe e.
Nigba to n kede pe inu gbọngan tilu Aran-Orin ni eto naa yoo ti waye, o ṣalaye pe ko nii si ojusaaju, bẹẹ si ni wọn ko nii wo oju, ko to di pe wọn fun awọn eeyan lowo ọhun.
Akewejẹ sọ pe awọn araalu yoo gba owo naa, lai nii ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa, to si jẹ ko di mimọ pe oun farajin si idagbasoke ati igbayegbadun awọn eeyan oun kaakiri ilu ati igberiko
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Akewejẹ fi ẹgbẹrun mẹwaa naira naa da awọn Opo ati arugbo lọla ni Wọọdu keji tilu Oro, iyẹn nibi ipade awọn alẹnulọrọ ti wọn ṣe.
Nibẹ ni Akewejẹ, ẹni to tun fẹẹ jade du ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara ninu eto idibo ọdun 2027, fidi rẹ mulẹ pe awọn Opo ati arugbo ti ko din ni ẹgbẹrin, iyẹn 800 ni yoo jẹ anfaani owo ọhun to pe ni Owo Arugbo.
O jẹ ko di mimọ pe lati ma jẹ ki agbekalẹ Owo Arugbo naa Gomina AbdulRazaq bẹrẹ rẹ labẹ eto ti wọn pe ni Kwara State Social Investment Programme parun lojiji, lo fa a, toun naa fi gun le e.
Siwaju sii lo fi da awọn eeyan loju lẹẹkan sii pe oun yoo tubọ fi ara jin lati maa ṣe iranwọ fun awọn to ba ku diẹ kaato fun lawujọ.
No comments:
Post a Comment