Mo farajin lati sin awọn eeyan mi nijọba ibilẹ Ọdẹda pẹlu irẹlẹ - Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 15, 2026

Mo farajin lati sin awọn eeyan mi nijọba ibilẹ Ọdẹda pẹlu irẹlẹ - Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun sọrọ


Lẹyin gbogbo faakaja nidi oṣelu, nipa ẹni yoo lọ ṣoju agbegbe Odeda nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, awọn agbaagba nijọba ibilẹ naa ti wa fẹnu ko lati jẹ ki olori ile igbimọ aṣofin, Ọnarebu Oludaisi Olusegun Elemide pada lọ.

Kii ṣe igba akọkọ, tabi ẹẹkeji ree ti Onarebu Elemide yoo maa ṣoju awọn eeyan naa nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, ṣugbọn to jẹ igba akọkọ ti yoo di olori ile igbimọ naa.

Lati bi ọsẹ meloo kan ni awọn kan nijọba ibilẹ naa ti n fẹhonu han pe awọn fẹ ki aṣoju miran jade, ati pe ipo ọhun ko si fun ẹnikan ṣoṣo.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn ko fẹ Ọnarebu Elemide mọ, lawọn miran n sọ pe ẹni ti awọn fẹ niyẹn, nitori pe latigba to ti n ṣoju awọn ni ko ti foju wọn gbolẹ, to si n ṣe daadaa.

Wọn ni iwuri nla lo tun jẹ pe ipo olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun wa ni akoso awọn, ti Ọnarebu Elemide si n lo ipo naa bo ti tọ, paapaa fun idagbasoke agbegbe wọn..

Nibi ipade awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ẹgbẹ naa to waye l'Ọjọbọ to kọja, ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni agbegbe naa ti wa fẹnu ko pe ki Ọnarebu Oludaisi Ẹlẹmide pada sipo naa.

Wọn lawọn nigbagbọ ninu ipo adari rẹ, nitori pe ko si ojusaaju ninu iṣakoso rẹ latigba to ti wa nipo ọhun.

Nigba toun naa n fi idupẹ rẹ han, Ọnarebu Elemide gbe oṣuba kare fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ, o si lo jẹ nnkan iwuri pe wọn tun nigbagbọ ninu oun lẹẹkan sii.

"Lonii, mo da gbogbo ogo, ọla ati iyin pada sọdọ Olorun Alagbara, Ẹni ti oore-ọfẹ, aanu, ati oju rere atokewa rẹ tun sọrọ fun mi lẹẹkan sii. Lotitọ, nigba ti Ọlọrun ba fi ontẹ lu irin-ajo kan, ko si agbara naa to le da ifarahan rẹ duro," Ọnarebu Elemide sọ bẹẹ.

O dupẹ lọwọ Gomina Dapo Abiodun fun ilana idari rẹ, atilẹyin baba, ati imọ oṣelu, to fi mọ ifarajin lati jẹ ki iṣọkan ati alaafia di ẹgbẹ naa mu ṣinṣin kaakiri ipinlẹ Ogun.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Arẹmọ Olusegun Osoba fun aduro ti rẹ, to si ni ipa to n fi lelẹ lo n ṣe iranwọ fun wọn ninu iṣẹ isin ilu.

Ọnarebu Elemide ko ṣai dupẹ lọwọ Sẹnetọ Solomon Olamilekan Adeola tọpọ mọ si Yayi, iyẹn aṣoju ti yoo gbe asia ẹgbẹ APC fun ipo gomina ninu eto idibo lọdun 2027, lori akitiyan tiẹ naa.

Siwaju sii lo fi imọriri han si gbogbo awọn adari kaakiri ijọba ibilẹ Odeda, awọn araalu, to fi mọ awọn Babalọja, Iyalọja at'awọn ọdọ lapapọ.

O wa ṣeleri pe oun ko tun ni doju ti wọn dun anfaani tuntun ti wọn gbe le oun lọwọ fun igba miran

"Bi mo ṣe yege gẹgẹ bi ọmọ oye lati dije sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, lẹkun Odeda kii ṣe aṣeyọri emi nikan, bi ko ṣe pe aṣeyọri fun iṣọkan itẹsiwaju, idagbasoke ati erongba gbogbo awọn eeyan wa ti wọn ni afojusun fun ilọsiwaju ati aṣoju to lagbara."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI