Ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited lo tun ti gbarada nibi akanṣe eto ti wọn pe ni Africa ESG Conference and Nigeria Project Expo, ti ọdun 2026.
Ipade naa, ẹlẹkẹwaa iru rẹ lo waye laipẹ yii, nibi ti awọn agbaagba nidi idasilẹ okoowo kaakiri ilẹ Afrika ti peju.
Awọn oludaṣẹsilẹ, aṣoju ijọba, olori ileeṣẹ ati awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka to n ri si dukia, ile kikọ, iṣẹ akanṣe ati eto iṣuna ko gbẹyin nibẹ.
Nigba to n sọrọ, Aarẹ Adetola EmmanuelKing to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ naa sọ pe awọn ti ko ipa ribiribi lati rii pe awọn eeyan di onile lori lai laagun tabi daamu.
Aarẹ EmmanuelKing, ẹni ti alakoso ati alabojuto ileeṣẹ naa, Adenike Ajobo ṣoju fun jẹ ko di mimọ pe gbogbo igba ni awọn n ri daju pe alafo ile gbigbe di pa.
O wa kan saara si awọn to sagbekalẹ eto ọhun, fun ipa ribiribi ti wọn n ko, lati ọdun mẹwaa sẹyin.
Alakoso ẹka to n ri sọrọ ọja tita ati ipolowo, Teddy Babatunde, tọka si ilana owo sisan fun oṣu mẹrindinlogoji lati fi san owo dukia ti awọn onibara wọn ba ra.
Babatunde tun sọ pe awọn onibara ni ẹka Vitco n lo ọgọrun-un oṣu lati fi san owo dukia wọn.
O ni ọna yii ni awọn onibara wọn n gba lati di larinlọọdu, lai jẹ ki bukata wọ wọn lọrun.
Bakan naa, Rosemary Onyediri to jẹ alakoso ẹka ti wọn pe ni Southern Super Cluster rọ awọn olokoowo lati lo asiko perete to ku nilẹ , ki wọn fi jẹ awọn anfaani to wa nilẹ.

No comments:
Post a Comment