Lojuna lati jẹ ki imugbooro ba iṣẹ ati ọja wọn, ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited tun ti tọwọ bọwe adehun nipa ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu ileeṣẹ Niger Foods Breeding and Feedlot Center.
Nibi abẹwo ti alaṣẹ ati oludasilẹ Adron Homes, Aarẹ Adetola EmmanuelKing ṣe lọ si ileeṣẹ naa laipẹ yii, ni wọn ti fẹnuko lori adehun tuntun ọhun.
Igbesẹ yii ko ṣai waye, bi ko ṣe lati ṣe agbelarugẹ fun iṣẹ agbẹ ati ọgbin, fun ounjẹ lati pọ yanturu laaarin ilu.
Abẹwo yii la gbọ pe wọn ti foju sọna fun awọn anfaani to wa ni ẹka ohun ọsin.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ileeṣẹ Adron Homes ti n foju sọna fun idasilẹ ileeṣẹ Adron Farm Estates kaakiri ipinlẹ Niger.
Adron Homes ti ọpọ mọ gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ṣoowo ile, ilẹ ati dukia kaakiri Naijiria, ni wọn tun ti fẹẹ lọ sinu iṣẹ agbẹ bayii, fun idagbasoke ba ẹka naa kaakiri Naijiria.
Eyi ni wọn yoo fi maa mu imugbooro ba awọn agbegbe, lati pese agbekalẹ awọn iṣẹ akanṣe fun okoowo iṣẹ agbẹ, ohun ọsin ati ipese ounjẹ.

No comments:
Post a Comment