Bo tilẹ jẹ pe ohun to ṣokunfa iku ọkan lara awọn ọga ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Ogun tẹlẹ, Alaaji Akeem Abodunrin tọpọ awọn eeyan mọ si Iyeru ṣi n ruju, sibẹ, ibanujẹ nla lo jẹ fun awọn ẹbi ẹ, paapaa awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ.
Alẹ ọjọ Aiku to kọja, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni iroyin iku Iyeru jade sori ikanni ayelujara.
Ọpọ awọn eeyan lo si ti bẹrẹ sii fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si awọn mọlẹbi oloogbe, paapaa awọn to sunmọ ọn.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ijọba ipinlẹ Ogun tabi ẹgbẹ awakọ ko tii fi atẹjade sita lati fidi iroyin naa mulẹ.

No comments:
Post a Comment