Ijọba ipinlẹ Ogun buwọ lu Osunsina gẹgẹ bi Olu Ifo tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 13, 2026

Ijọba ipinlẹ Ogun buwọ lu Osunsina gẹgẹ bi Olu Ifo tuntun

Orin ọpẹ lo gba ẹnu awọn araalu Ifo, ijọba ibilẹ Ifo nipinlẹ Ogun, nigba ti Gomina Dapọ Abiodun buwọ lu ọba tuntun fun wọn.

Gbajugbaja oniṣowo ilẹ ati dukia nni, Ọtunba Olumide Atanda Osunsina ni ijọba ipinlẹ naa sọ pe yoo gori itẹ awọn baba nla rẹ.

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni ọba ana, Oba Samuel Atanda Oladipupo JP, tẹri gbaṣọ.

Latigba naa ni igbesẹ ti bẹrẹ lati yan ọba tuntun, nigba ti igbimọ awọn oloye ilu panupọ pẹlu awọn Afọbajẹ.

Bi wọn ṣe yan Osunsina la gbọ pe o lọ ni ibamu pẹlu aṣa, ilana ati iṣe ilu Ifo, to fi mọ ibamu pẹlu iwe ofin oye ati ọba jijẹ nipinlẹ Ogun.

Ọba tuntun yii ni yoo jẹ Oṣomẹkun akọkọ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI