Ọba MacGregor dide lati f'opin si wahala awọn agbẹ ati darandaran l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 2, 2026

Ọba MacGregor dide lati f'opin si wahala awọn agbẹ ati darandaran l'Ogun


Lojuna lati fi opin si wahala to n koju awọn agbẹ lati ọdọ awọn darandaran nipinlẹ Ogun, paapaa niluu Ilawo, Ọba Alexander Olusegun MacGregor ti sọ pe opin gbọdọ de.

Ọba MacGregor sọ pe asiko to fawọn agbẹ lati maa ṣiṣẹ oojọ wọn lai si idiwọ tabi iṣoro, lati le jẹ ki ounjẹ pọ yanturu lorileede Naijiria.

L'Ọjọru, ọsẹ yii ni ipade awọn alẹnulọrọ waye ni aafin Olu Orile-Ilawo to wa niluu Abeokuta waye, nibi ti awọn aṣoju ijọba, aṣoju awọn darandaran, to fi mọ awọn agbofinro ti peju.

Yatọ si awọn wọnyi, gbogbo awọn agbaagba, to fi mọ awọn ọdọ kaakiri abule mẹtadinlọgọjọ (157) to so ilu Ilawo papọ ni wọn wa nibi ipade ọhun.

Nibẹ ni wọn ti tọwọ bọwe lati gba alaafia ati iṣọkan laaye laaarin ilu, ki ohun gbogbo le maa lọ letoleto.

Ko sohun meji to fa ipade yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni pati fi opin si awọn aawọ ati rogbodiyan to n ṣẹlẹ laaarin awọn darandaran ati awọn agbẹ lawọn abule wọnyi, eyi ti wọn lo ti n kọja ohun ti ẹnikẹni ko lero.

Oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Ogun lori eto aabo, Olusola Subair; amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori ọrọ awọn ẹya, Hadi Sani; igbakeji ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Adaramola Felix lo wa nibi ipade naa.

Yatọ si Ọba MacGregor at'awọn oloye rẹ, aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, S.O. Ogunleye at alaga ẹgbẹ Miyetti Allah nipinlẹ naa, Alaaji Abubakar Ibrahim Dende ko gbẹyin nibẹ.

Nigba to n sọrọ, Alayeluwa sọ pe erongba oun ni lati jẹ ki alaafia ati iṣọkan jọba lawọn abule ati ilu toun jẹ ọba lori wọn, fun idagbasoke ati ilọsiwaju.

Kabiyesi naa sọ pe ọna abayọ toun ri, ni lati pe gbogbo awọn tọrọ naa kan papọ, ki onikaluku sọ ẹdun ọkan, lati le fi opin si aawọ to n dide.

O.wa rọ gbogbo wọn lati gba alaafia laaye, pẹlu bo ṣe sọ pe ko si ẹni ti ọkan rẹ yoo balẹ nigba ti wahala ba n fi ojoojumọ ṣẹlẹ niluu.


Nigba to n gba ẹnu awọn ara abule naa sọrọ, Olakunle Akindele lati abule Ola ṣalaye nipa bi awọn Fulani ṣe n da ẹran wọnu oko lati jẹ ire oko ti wọn n fojoojumọ laagun lati da.

O ni eto ọrọ aje awọn ni oko ti awọn n da, ko si bojumu ki awọn kan maa fi eto ọrọ ti wọn, dunkooko mọ awọn lori ilẹ ajogunba wọn.

Bakan naa lo tun sọ pe omi ti gbogbo ilu n mu, ni awọn darandaran naa ati awọn ẹran wọn n ṣe idọti si ni gbogbo igba, to si ni wọn ko gbọ ikilọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Alhaji Abubakar Ibrahim Dende to jẹ alaga ẹgbẹ Miyetti Allah nipinlẹ naa rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn tọrọ kan, to si ṣeleri pe ayipada rere yoo wa lẹyin ipade naa.

Adaramola Felix wa ṣe ikilọ fun gbogbo awọn araalu to n ṣe idajọ lọwọ ara wọn nigba ti ipenija ba dide, to si ni ẹni tọwọ ba tẹ yoo foju winna ofin, lai wo iru ẹya tabi eeyan ti ẹni naa jẹ.

Felix sọ pe ki ẹnikẹni to ba kofiri iwa to nii fura si, tete fi to awọn agbofinro leti, ki wọn ba a le gbe igbesẹ to yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI