Ijọba apapọ ni lati ja owo epo lọ silẹ, NLC ṣatilẹyin f'awọn oṣiṣẹ nilẹ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 22, 2026

Ijọba apapọ ni lati ja owo epo lọ silẹ, NLC ṣatilẹyin f'awọn oṣiṣẹ nilẹ Naijiria


Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ Naijiria, NLC ati gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba patapata labẹ ẹgbẹ ti wọn pe ni Joint National Public Service Negotiating Council, JNPSNC, to fi mọ Trade Union Side, ti parọwa sijọba apapọ lati ja owo epo rọbii lọ silẹ.

Wọn lawọn n fẹ ki owo jaala epo bẹntiroolu ja silẹ si ẹẹdẹgbẹta naira, lati le mu adinku ba iṣoro ati ilakaka to n dojukọ awọn oṣiṣẹ ati gbogbo awọn to gbe ara le wọn.

Bakan naa ni wọn lawọn n fẹ afikun owo oṣu to kere julọ, eyi ti yoo jẹ ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira.

Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ JNPSNC, Olowoyo Gbenga buwọ lu, eui ti wọn fi ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu, lo ti sọ pe awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ n fẹ lati ba aarẹ ṣepade lori owo oṣu to kere julọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI