Apa kan ile alaja marun-un da wo l’Abuja, ẹnikan farapa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 19, 2026

Apa kan ile alaja marun-un da wo l’Abuja, ẹnikan farapa


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara adugbo Durban to wa ni agbegbe Wuse keji niluu Abuja, nigba ti apakan ninu ile alaja marun-un kan deedee da wo lojiji.

Nnkan bi agogo mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ Abamẹta, opin ọsẹ to kọja yii la gbọ pe ile naa da wo.

Ẹnikan ṣoṣo to wa nitosi agbegbe ile naa ti wọn ṣi n kọ lọwọ lo farapa.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nilẹ Naijiria, National Emergency Management Agency, NEMA, fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade ti awọn alakoso fi sita.

Ninu atẹjade ọhun ti ẹka ileeṣẹ iroyin rẹ buwọ lu, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn ara agbegbe naa ni wọn ta awọn lolobo.

Wọn ni loju ẹsẹ ti wọn ti ranṣẹ pe awọn, ni awọn oṣiṣẹ wọn ti sare lọ sibẹ lati ṣe iranwọ to yẹ.

NEMA ṣalaye pe ileeṣẹ awọn pẹlu awọn ileeṣẹ panapana ati ileeṣẹ pajawiri AYA lo sare debẹ lati ṣe iranwọ to yẹ.

Wọn fidi rẹ mulẹ pe ko sẹni kankan to ba iṣẹlẹ naa lọ, bo tilẹ jẹ ẹnikan ṣoṣo pere lo farapa, ati pe ẹni naa ti wa nibi to ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI