Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti sọ pe oun ni igbagbọ atii igboya wi pe oun yoo bori ninu eto idibo sile igbimọ aṣofin ilẹ Naijiria lọdun 2027.
Bello sọ pe oun yoo fidi akẹgbẹ oun to n di ipo ọhun mu lọwọlọwọ lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa, Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan janlẹ.
Gomina tẹlẹ naa lo n dije du ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kogi labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nigba ti Sẹntọ Natasha n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP).
Bi ẹ ko ba gbagbe, oniruuru ẹsun ni awọn oludije mejeeji yii ti fi kan ara wọn, ti ọpọ si mọ daju pe wọn ko gba ti ara wọn, paapaa nidi oṣelu, koda ti wọn tun ti pe ara wọn lẹjọ.
Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, Yahaya Bello fẹsun kanNatasha Akpoti-Uduaghan wi pe o mọ nipa ikọlu to waye niluu Ajaokuta, ati bi awọn ẹlẹwọn ṣe ja ọgba ẹwọn Kuje.
Awọn iṣẹlẹ mejeeji yii lo waye laaarin oṣu Kẹfa si oṣu Keje, ọdun naa.
Loju ẹsẹ ni Akpoti-Uduaghan ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa awọn ẹsun ti Bello fi kan oun, niori pe ilẹ Amẹrika loun wa lori oyun ati ibimọ toun ba lọ.
Bakan naa lọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 naa, Akpoti-Uduaghan ṣapejuwe Bello gẹgẹ bi apaniyan ati ijamba fun awọn ara ipinlẹ Kogi, nigba to n sọrọ lori ẹsun ti gomina tẹlẹ ọhun fi kan an.
Ju gbogbo rẹ lọ, Bello nigba to n sọrọ lori eto oṣelu ileeṣẹ TVC, Bello sọ pe oun ni igboya kikun lati fidi akẹgbẹ oun lẹgbẹ oṣelu alatako janlẹ.
“Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2027 ti fẹẹ de, esi ibo yoo si sọrọ funra rẹ.
“Ẹ jẹ ki ọjọ naa de, ko si kọja lọ, aṣeyọri alailẹgbẹ yoo de ba Yahaya Bello, gomina tẹlẹ ni Kogi, ati fun ẹgbẹ oṣelu APC,” o sọ bẹẹ.

No comments:
Post a Comment