Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) nipinlẹ Jigawa, Sabo Muhammad Nakudu, ti sọ pe asiko to fun iṣakoso Aarẹ Bola Tinubu lati maa palẹmọ ẹru rẹ pada sile.
Nakudu sọ pe latigba ti Aarẹ Tinubu ti gba ijọba lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 ni ara ti n ni awọn ọmọ Naijiria.
O ni asiko iya ti awọn araalu n jẹ latigba ti Tinubu ti de ipo Aarẹ ti to gẹ, nitori pe nnkan ko gbọdọ maa lọ bayii.
Agba oloṣelu naa lo sọrọ yii ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara ti Facebook rẹ lọjọ Aiku to kọja.
Nibẹ lo ti fi ẹsun kan iṣakoso Tinubu wi pe o mọ-ọn-mọ maa fi ara ni awọn araalu, nipasẹ awọn ilana ati agbekalẹ rẹ to tako igbayegbadun araalu.
Bakan naa lo sọ pe o ṣe pataki lati tete ri si eto ọrọ aje to le koko fun gbogbo ọmọ Naijiria latari owo iranwọ ori epo ti ijọba naa yọ kuro.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni latigba ti iṣakoso APC ti kede yiyọ owo iranwọ ori epo lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ sii jiya.
Bakan naa lo sọ pe bi iṣakoso Tinubu ṣe kede adinku lori owo jaala epo fun oṣu kan kii ṣe ohun to boju mu rara, to si ni awọn araalu lẹtọ si ohun to dara ju bayii lọ.

No comments:
Post a Comment