Gabriel to lọ ji irin ipo adugbo gbe ha sọwọ ẹṣọ aabo So-Safe l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 12, 2026

Gabriel to lọ ji irin ipo adugbo gbe ha sọwọ ẹṣọ aabo So-Safe l’Ogun


‘Ẹ ṣe m I jẹjẹ, ẹ foju aanu wo mi’ lọrọ abamọ to n jade lẹnu gendekunrin kan tọwọ ẹṣọ aabo ipinlẹ Ogun tẹ lọsẹ to kọja yii.

Friday Amos Gabriel lorukọ gendekunrin naa, ẹni ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju ko maa jale lọ.

Ọsẹ to kọja yii lọwọ palaba Amos segi, ladugbo kan to ti lọ ji irin nla gbe nibẹ.

Nnkan bi agogo mẹfa aabọ, aarọ kutu ọjọ naa, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 la gbọ pe wọ adugbo Mosa to wa nitosi odo Balogun, agbegbe New Life niluu Ilogbo, ijọba ibilẹ Ifo.

Wọn ni ibi to ti n gbe irin naa lọ, lọwọ awọn ara adugbo ti tẹ ẹ, ti wọn si beere ibi to ti n gbe e bọ, ṣugbọn ti wọn ni ko le dahun.

Alaga adugbo naa, Ọgbẹni Akinbobola ni wọn lo ranṣẹ si awọn ẹṣọ aabo So-Safe Corps lati wa a wo afurasi ole ti wọn mu.

Loju ẹsẹ ti awọn So-Safe Corps naa ti debẹ, ni wọn ti gbe e lọ ibudo wọn lati fọrọ wa a lẹnu wo

Nibẹ lo ti jẹwọ pe agbegbe Mosa si odo Balogun loun ti ge irin ti wọn fi ṣe opo naa, pẹlu erongba lati lọ ta a lowo pọọku.

Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ rẹ ni iPhone kan, tikẹẹti tẹtẹ to jẹ ẹgbẹrun marun din ni ọgọrun kan (N4,900) naira, aṣọ meji, abẹfẹlẹ meji, ina igbalode to fi n reran ṣiṣẹ loru, ati awọn nnkan miran.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ So-Safe Corps, Adegunwa Adegbuyi fi sita fawọn akọroyin, o ni awọn ti fa afurasi naa le awọn ọlọpaa SWAT, ẹkun Base 5 lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori rẹ.

Adegbuyi sọ pe ọga awọn Soji Ganzallo ti gbe oṣuba kare fun awọn ara adugbo naa lori iwa ojulalakanfinṣọri ti wọn hu, ati bi wọn ko ṣe fi idajọ sọwọ ara wọn.

O rọ awọn araalu lati ma ṣe fi idajọ sọwọ ara wọn nigba ti wọn ba rọwọ to afurasi, ati pe ki wọn tete maa wa ni ikiyesara nipa awọn oju ajoji ti wọn ba n ri lagbegbe wọn, nipa fifi to awọn eleto aabo leti.

Bẹẹ lo fidi rẹ mulẹ pe aabo ẹmi ati dukia araalu jẹ ileeṣẹ wọn logun pupọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI