Nibi ti oro de duro bayii, bi awon oloye egbe oselu APC nipinle Ogun ko
ba tete da si wahala to n sele, o see se ki won maa lepa emi ara won, nitori bi
won se n fojoojumo koju ija si ara won.
Lati nnkan bi osu meloo kan seyin ni wahala ti n be sile ninu egbe oselu
APC nijoba ibile naa, laarin alaga won, Pasito Olawale Onaolapo atawon kan ti
won dipo oselu mu ninu ijoba Amosun.
Won ni ojoojumo ni won n wa ona lati da nnkan ru mo alaga won naa loju,
eyi gan an lo fara han ti won fi ja okunrin naa sihoho nita gbangba nilu Ota
lakoko ti won n se ayeye oku alaga egbe oselu APC nipinle Ogun, Oloye Adeniji,
Baba Komputa.
Se ni won lu okunrin naa bi eni lu bara leyin ti won ja sihoho tan lojo
naa, tawon eeyan si bere sii fi de yeye nibi isele naa.
Pasito Onaolapo jo je ki itiju naa dun oun, se lo muu Mora lai mo pe
nnkan to fee se wa ninu okan e, idi ni yi ti won fi loun naa ran awon toogi lo
sibi ayeye ibura awon kanselo to waye ni Odeda, tawon yen si sa awon eeyan lada
nibe repete.
Bakanna, irufee ija yii tun waye ni agbegbe Obantoko l'Abeokuta nibi
ayeye oku iya okunrin oloselu kan ti won n pe ni Olasehu. Ija naa waye laarin
Osiele ati alukoro egbe oselu APC nijoba ibile naa ti ma n pe ni Aro Shittu.
Won ko je ki won lu ara won ni Obantoko, sugbon nigba ti won de Adatan,
lawon mejeeji se bee koju ija sira won ti won lu ara won bo se wu won.
Awon kan so pe lakoto ti won n lu ara won ni akowe ijoba ipinle Ogun,
Taiwo Adeoluwa koja, sugbon iran lo n fi won wo, ko sokale ninu moto to fi lo
ni tie.
AWIKONKO gbo pe, okunrin kan to ti je alaga ijoba ibile ni Odeda tele,
ati agbejoro kan toun naa n se oselu, to n sise pelu Amosun ni won so pe o wa
leyin awon to n doju ija ko alaga egbe oselu APC nijoba ibile naa, iyen Pasito
Onaolapo.
Titi di akoko yii ni awon eeyan naa si leri sira won, ti won si ni
gomina gan an ko tii bawon da si, eyi lo faa tawon omo egbe APC fi je gbajari
pe ki won gba awon lowo awon toogi ti won ti n lepa emi ara won nijoba ibile
naa.
Bakanna ni won so pe owo obinrin kan to sese je alaga ijoba idagbasoke
ni Ilugun Odeda, Arabinrin Mofoluke Soremekun ko mo si wahala to n sele, oun
naa si wa lara awon to n fi toogi hale kaakiri igboro.
No comments:
Post a Comment