Idi ti Pasito Adeboye se yan alakoso ijo Ridiimu miran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 19, 2017

Idi ti Pasito Adeboye se yan alakoso ijo Ridiimu miran


Pasito Adeboye
Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yi ni oro agba iranse Olorun ti Olorun ti gba owo e sise amin ati ise iyanu lagbaye, eni to je oludasile ati alakoso ijo irapada, The Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasito Enoch Adejare Adeboye se deede so pe oun ko le tesiwaju mo lati maa je alakoso ijo naa lorileede Naijiria mo, to si yan, igbakeji e lati tesiwaju gege bi alakoso ijo naa si n je kayeefi fawon eeyan, paapaa awon omo ijo naa toripe ojiji loro naa ba won.

Bo tile je pe agba iranse Olorun naa ti n so tipe pe oun ko ni pee gbe ipo naa le fun elomin in ti yoo maa tesiwaju gege bi adari naa, sugbon lojiji loro naa bawon eeyan nitori pe won ko ro o ti tele, ko seni to ronu nipa e.

Orisirisi awuyewuye lo si ti n jeyo lati ojo Satide ojo keji osu yii nibi ipago awon iranse Olorun to waye ni Olu iya ijo naa to wa ni Simawa, ipinle Ogun nibi ti Pasito Adeboye ti so pe oun ko le tesiwaju mo gege bi alakoso ijo naa forileede Naijiria, sugbon oun si ni alakoso gbogbo ijo naa lagbaye.

Bi e o ba gbagbe, ojo keji osu keta odun yi ni Baba Adeboye yoo pe odun marundinlogorin, 75 loke eepe, odun karundinlogoji si re e ti iranse Olorun naa ti wa gege bi alakoso ijo naa. Eyi lawon kan si ro o pe o faa ti Pasito naa fi so pe ara ti n dara agba, baba fee sinmi ni.

Bawon kan se n so pe ofin kan ti won ni ajo kan, Financial Reporting Council (FRC) of Nigeria’s Code of Corporate Governance bu owo lu lasiko ijoba aare ana, Omowe Goodluck Jonathan lo fa ipinu ojiji naa, kawon ti won mo nipa ofin naa ma ba a fi ofin naa gbe e lo sile ejo lati le fipo naa sile ni kiakia, bo tile je pe gege bi ohun ti AWIKONKO gbo pe awon kan ti n finna mo Baba pe ko gbe akoso ijo naa felomiin.

Ofin naa ni won lo so pe, fenikeni to ba nileese aladani, gala soosi, mosalasi, tabi ileese yoo wu, iye odun ti yoo le lo lati je adari e ko gbodo ju ogun odun lo, ti yoo ba si fee gbe ipo naa sile, ko gbodo gbe fun molebi e kankan, ayafi eni ti kii se ebi e.

Ninu atejade ti awon agbaagba ijo Ridiimu fi sita lojo naa ni won ti je ko ye awon eeyan pe ohun ti ofin Naijiria so ni Baba Adeboye tele, to si je ko bowo fun gege bi Bibeli ti se so pe, "e tele ofin".

Gege bi AWIKONKO se gbo, okan lara awon agba Pasito, iyen Pasito Joseph Obayemi ni Baba Adeboye yan lati gba ipo naa, 

Olori ijo naa, Baba Adeboye so pe igbese naa ko seyin ti ofin toun bowo fun lati so Pasito Obayemi di alakoso ijo naa lorileede yii, sugbon oun loun yoo maa sakoso ijo naa lagbaye. Siwaju si ni baba Adeboye tun yan awon meji mi in, Pasito Johnson F. Odesola gege bi akowe gbogboogbo ijo naa, Pasito Joseph Adeyokunnu gege bi akapo.

Bakanna lo tun yan Pasito Odesola ati Pasito Adeyokunnu gege bi amugbalegbe ti yoo ba Pasito naa sise po. Bee lo wa ro awon omo leyin Kristi pe ki won ma se sa fun oselu, ki won si maa kun fun adura nigbagbo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI