E je ki idagbasoke je yin logun - Gbenga Daniel - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

E je ki idagbasoke je yin logun - Gbenga Daniel

Gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel ti gba ijoba orileede lamoran pe ki won je ki idagbasoke orileede yi je won logun ju ohunkohun lo lati le fi okan awon omo orileede ninu eto oro aje to denu kole.

Daniel soro yi lakoko to n ki awon araalu fun ti ajoyo odun tuntun ti a sese bo si yi nibe lo ti so pe ki ijoba lapapo, iyen ijoba ibile, ipinle ati ijoba apapo je ji idagbasoke je won logun ninu odun tuntun ti a sese bi si yi nitori pe ohun ti o se pataki julo niyen lakoko risesan yi.

O so pe awon idagbasoke bii ohun elo amusoro, ina, pipese ise fawon odo, ise agbeje, eto ilera, eto eko to see foju ri, awon ileese igbalode atawon mi in ti won se pataki lati mu ki idagbasoke de ba ilu ti o si le mu ayipada rere bawon eeyan orileede yii lapapo.

Otunba Daniel tun so pe awon nnkan amusoro ti Olorun fi ta wa lore lorileede yii je awon ohun amuyangan ti o to lati yi eto oro aje to denu kole yii si rere lai fi ti risesan ti a n pariwo yi se. O ni anfaani lawon nnkan naa je fun wa lati maa wo won gege ohun elo idagbasoke.


Bakanna lo gbawon araalu naa lamoran pe ki won maa se ohun gbogbo niwontunwonsi, ki won si ma se aseju ninu ohun ti won ba n dawole. Bee lo so pe kawon naa ri daju pe won n fowosowopo pelu ijoba nipa gbigba ladura si Olorun lati fun wa ni awon adari otooto ti won yoo sise won gege bi ise.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI