Tirela Dangote pa baba olokada ni Papalanto - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 9, 2017

Tirela Dangote pa baba olokada ni Papalanto

Won ni Olorun lo yo iyawo e naa

Bi eeyan ba je ori ahun, to ba de ibi isele buruku yii lojoru Wesde ose to koja nibi ti okan lara awon tirela Dangote ti gba baba agbalagba ti won lojo ori e ti le ni ogota odun to si ku lesekese, yoo sukun lojo naa.

 Gege bi AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago meta ku iseju meedogun nisele naa waye nigba ti won so pe ona Ilaro ni baba agba naa ti n bo pelu iyawo e lori okada.

Layipo Papalanto si Ilaro ni won so pe eni to wa tirela naa ti n bo pelu ere asapajude ti won lo n sa, ko too di pe igba ti yoo fi so pe koun gboju soke, aso ko ba omoye mo, o ti kan olokada naa lara.

Pati ni won so pe baba naa ati iyawo e ti n bo ko too di wipe won sagbako isele buruku naa, bo tile je pe egbe ona ni won so pe tirela naa ti loo ba won.

AWIKONKO gbo pe loju ese toro naa ti sele ni awako naa ti poora, ko seni to le so pe bo se rin in re, o ti na papa bora.

Leyin nnkan bi wakati kan aabo ni won so pe awon olopaa too gbe oku baba naa lo si mosuari jenera osibitu to wa ni Ifo.

Bo tile je pe iyawo baba agba naa toun naa ti le ni aadota odun ti won jo wa lori okada ko farapa, sugbon ekun to n sun ni pe nibo loun fee gba, eru eeyan meji ti di toun.


Titi di bi a ti n ko iroyin yi jo lawon olopaa si n wa awako naa bo tile je pe won ti wa tirela naa lo si ago won lati tesiwaju lori ise iwadi won, gege bi a se gbo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI