OHUN TI E O MO NIPA EBENEZER OBEY FABIYI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 5, 2017

OHUN TI E O MO NIPA EBENEZER OBEY FABIYI

Ojo keta osu kerin odun 1942 (April 3rd, 1942) ni won bi Ebenezer nilu Idogo, ipinle Ogun. Omo ilu Abeokuta ni nitori pe Egba ni Baba e, nigba ti iya e je omo Owu.
Oruko ti baba ati iya e so ni: Ebenezer Remilekun Aremu Olasupo Obey-Fabiyi.

Ebenezer Obey-Fabiyi
BO SE BERE ISE ORIN
Nigba to wa ni kekere ni iya e ti maa n gbe lo si soosi, to si je pe to ba ti gbe sile pe ko sere, ibi tawon akorin n joko si lo maa ra lo, to si ma lo maa da awon irinse ti won n lo ru. Bo se n dagba lo n laju si orin, to si darapo mo egbe akorin ni ile iwe Methodist to wa ni Idogo, iyen nijoba ibile Yewa South nibi to ti ka ileeko alakobere.

Yato si wipe o wa ninu egbe akorin nile iwe, o tun wa ninu egbe akorin ninu ijo to n lo nigba naa. Lakoko naa lo n jinle si ninu ise orin to si je pe awon ala to n la nigba naa, bi yoo se dagba ninu ise orin kiko ni.

Ebenezer Obey Fabiyi ni won fi se adari egbe olorin kan tawon odo nilu Idogo da sile, eyi ti won pe ni Ifelodun Mambo Orchestra. Leyin naa loun naa da egbe ti e sile lodun 1957, egbe naa lo pe ni Royal Mambo Orchestra. Ko pe to da egbe yi sile lo ko gbogbo irinse e, to si gba ilu Eko lo.

Gbajumo olorin kan naa wa nigba naa Taye n gba ti e, Adeolu Akinsanya loruko e, orin juju lo n ko. Orin e wa lara awon orin ti Ebenezer Obey n gbo to si ma n wu lori. Eyi lo je koun naa maa wo awokose baba naa, to si bere sii korin bii ti e, sugbon, ko geeti e daadaa, eyi lo mu pinu lati sunmo Alagba Akinsanya yii lati le ko eko siwaju sii nipa orin. Baba yi lo tubo ran lowo lati le se aseyori siwaju si ninu ise orin to yan laayo.

Nigba to to asiko kan, loun naa wo pe ona wo loun tun le gba lati mu ki orin toun yato si awon orin juju toku, eyi lo muu ronu lati gba ona ara miran yo sawon eeyan paapaa awon ololufe e atawon ti won jo n figagbaga, to si mu MILIKI wonu e.

Nigba to ya lo tun tesiwaju lati darapo mo egbe olorin ti Oloogbe Fatai Rolling Dollar  da sile, ko too tun da  egbe miran sile to pe ni The International Brothers, iyen  lodun 1964 nibi to ti n play highlife fun won. Sugbon lodun 1970 lo tun gbe egbe naa goke agba to si yi oruko e pada si Inter-Reformer. Oruko egbe yi lo fi se awon orin jade to kun fun opolopo track to si mile Afrika titi, bee ni won tun fun ni West African Decca musical label.

Ilu, gita ati gangan to fi kun orin e lo je kawon to gbo Faaji feran lati maa gbo orin e, ki won si maa milengbe. Odun 1990s lo feyinti ninu ise orin to n ko tele, ko too di pe Olorun pe, o si n korin igbagbo.

Yato si wipe Oloye Ebenezer padanu akaimoye awon awo orin to ti se atawon eyi to fee gbe jade nibi ijamba ina kan to jo ile ise e, iyen DeCross lodun 1995, sibe, ko lonka lawon orin e to si wa di asiko yi taye si n gba ti e.


LARA AWON ORIN TO TI GBE JADE NI:
1964 - Ewa Wo Ohun Ojuri
1965 - Aiye Gba Jeje b/w Ifelodun - Gari Ti Won b/w Orin Adura
1966 - Awolowo Babawa Tide b/w Oluwa Niagbara Emi Mi*Palongo b/w Teti Ko Gboro Kan*Oro Miko Lenso b/w Orin Ajinde*Late Justice Olumide Omololu b/w Iyawo Ti Mo Ko Fe
1967 - Olomi Gbo Temi b/w Maria Odeku*To Keep Nigeria One b/w Awa Sope Odun Titun*Edumare Lon Pese b/w Omo Olomo*Ope Fun Oluwa b/w Paulina
1968 - Ore Mi E Si Pelepele b/w Ajo Ni Mo wa*Ijebu L'ade b/w Lati Owolabi*Col. Ben Adekunle b/w Ori Bayemi*Lolade Wilkey b/w Adetunji Adeyi*Gbe Bemi Oluwa b/w Olowo Laiye Mo
1969 - Ode To Nso Eledumare b/w Pegan Pegan*Sanu-olu b/w K'Oluwa So Pade Wa*London Lawa Yi b/w Oro Seniwo*Isokan Nigeria / etc.*Eni Mayo Ayo / etc1969/1970*Emi Yio Gbe Oluwa Ga b/w Ise Teni
1970 - Lawyer Adewuyi*Ala Taja Bala b/w Ohun Toluwa Ose*Ogun Pari / etc.*In London*On The Town
1971 Ija Pari (Part One) b/w Ija Pari (Part Two)*Esa Ma Miliki b/w Awon Alhaji*Face to Face b/w Late Rex Lawson*Oro Nipa Lace b/w Yaro Malaika
1972 Late Oba Gbadelo II*Board Members*Vol.4: Aiye Wa A Toro*In London Vol. 3*Odun Keresimesi
1973 And His Miliki Sound*The Horse, The Man and His Son*E Je Ka Gbo T'Oluwa*Adeventure of Mr. Music*Mo Tun Gbe De
1974 Inter-Reformers A Tunde*Eko Ila*Around the World*Iwa lka Ko Pe
1975 Mukulu Muke Maa Jo*Ota Mi Dehin Lehin Mi*Alo Mi Alo*Edumare Dari Jiwon
1976 Late Great Murtara Murtala Ramat Muhammed*Operation Feed The Nation
1977 Eda To Mose Okunkun*Immortal Sings for Travellers*Adam and Eve
1978 Igba Owuro Lawa*Oluwa Ni Olusa Aguntan Mi*No Place Be Like My Country Nigeria
1979 In the Sixties Vol.1*In the Sixties Vol.2*Igba Laiye*Sky*E Wa Kiye Soro Mi*Omo Mi Gbo Temi
1980 Leave Everything to God*Current Affairs*Sound of the Moment*Eyi Yato
1981 Joy of Salvation*What God Has Joined Together
1982 Celebration*Austerity*Precious Gift
1983 Ambition*Singing for the People*Greatest Hits Vol. 3*Je Ka Jo*Thank You (Ose)
1984 The Only Condition to Save Nigeria*Solution*Peace1985*Security*My Vision
1986 Gbeja Mi Eledumare*Satisfaction*Providence
1987 Aimasiko*Immortality*Victory*Patience
1988 Determination*Vanity
1989 Formula 0-1-0*Get Yer Jujus Out
1990 Count Your Blessing*On the Rocket
1991 Womanhood
1993 Good News
1994 I Am a Winner*Walking Over (1994 ?)
1995 The Legend
1999 Millennial Blessings
2000 Promised Land
2002 Ase Oluwa
Aimasiko 2006
The Horse, The Man & ... 2006
Gbebe Mi Oluwa 2006
Oro Seniwo 2012
Iba F'Oluwa/Ajokodabi ... 2012
Ori Mi Koni Buru 2006
Ota Mi Dehin 2006
Anjade Loni Eledumare 2006
Baba Loran Mi Wa 2012


LARA AWON OLORIN TI WON JO N FIGAGBAGA LODUN NAA LOHUN
King Sunny Adé
Shina Peters
Orlando Owoh
Onyeka Onwenu
Victor Uwaifo
Sonny Okosun
Chief Stephen Osita Osadebe
Victor Olaiya

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI