Gongo so lojo ti Ebenezer Obey Fabiyi sayeye ojo ibi e l’Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 3, 2017

Gongo so lojo ti Ebenezer Obey Fabiyi sayeye ojo ibi e l’Abeokuta

Titi di bi a ti n koroyin yi lopo awon eeyan lo si n royin ayeye ojo ibi odunmarundinlogorin ti Gbajugbaja Onkorin Juju-Miliki nni, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi se ninu ijo Chapel of Christ the Glorious King to ninu ogba ile ikawe Olusegun Obasanjo to wa lagbegbe Oke-Mosan nilu Abeokuta.

Oloye Ebenezer Obey-Fabiyi
Awon ojise Olorun bii Pasito Enoch Adeboye ti ijo Ridiimu, Bisoobu Wale Oke to je igbakeji aare PFN; olori ijo CAN tele, ayo Oritsejafor ni won wa nibi ayeye ojo ibi lojo naa lati gbadura fun Oloye Ebenezer Obey, ti won si fi oro iyanju boa won eeyan.

Awon Oba alade bii Ooni Ile Ife, Ogunwusi; Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo; Osile ti Oke Ona, Oba adedapo Tejuoso. Iyalode ile Yoruba, Alaba Lawson naa jokoo nibi ayeye naa.

Bakanna ni awon Gomina tele nipinle Ogun bii Oloye Olusegun Osoba ati Otunba Gbenga Daniel ko gbeyin nibe nigba ti awon oloselu bii Senato Lanre Tejuoso; Onarebu Mudashiru Obasa to je olori ile igbimo asofin nipinle Eko; Ishola Adekunbi, olori ile igbimo asofin ipinle Ogun naa wa nikale.

Awon olorin igbagbo bii Mama Bola Are, Funmi Aragbaye, Yinka Ayefele, Tope Alabi. Atawon agba olorin bii King Sunny Ade, Salawa Abeni, Alabi Pasuma, Dele Abiodun, Adewale Ayuba, Sefiu Alao, Haruna Ishola, Tony Okoroji, Sunny Nneji, YK, Ruggedman atawon min in naa wa nikale.

Lakoko ayeye naa ni Gomina Ibikunle Amosun ti seleri pe oun yoo se eto bi won yoo se ka ile kan to je pe awon orin Ebenezer Obey Fabiyi atawon agba olorin miran yoo se wa nibe to je pe yoo da bi ibi igbafe fawon eeyan lati wa maa gbafe.

Amosun so pe boun ba ji laaro, orin Obey loun yoo koko gbo koun to lo si ofiisi nitori pe o kun fun ogbon, imo ati oye, bakanna lo kun fun opolopo imoran ati iwaasu ti ko se e ko danu. Bee lo tun so pe igbakigba toun ba lo silu Oyinbo loun maa n ri awon orin Ebenezer Obey, eyi lo je koun mo daju pe kii se awon omo Naijira nikan ni won n jegbadun e, awon oyinbo gan an daamo.

Siwaju akoko yin i Aare teleri lorileede yi, Oloye Olusegun Obasanjo ti gbosuba kare fun olojo ibi naa pe opo awon orin e lo se oun lanfaani lati se aseyori laye, paapaa lakoko to wa gege bi aare nigba ologun ati ninu ijoba alagbada.

Obasanjo so pe, boun baa n ronu, orin Obey loun maa n gbo lati fi pa ironu oun re titi digba toun yoo fi gbagbe sun lo.

Pasito Adeboye naa soro, o so pe, igba akoko toun yoo fi ogba ijo Ridiimu sile lati lo sibi ayeye niyii, atipe o ni bo se je. O loun le so pe asiko kan naa loun ati Oloye Ebenezer Obe Fabiyi jo gba Jesu gege bi Olugbala won, atipe opo awon orin e lo ti se oun naa ni anfaani to po repete, to si je koun naa wa lori ijokoo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI