E yee ja nitori awon oloselu o – Oba Akiolu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 31, 2017

E yee ja nitori awon oloselu o – Oba Akiolu

Eleko tilu Eko, Oba Rilwan Akiolu ti rawo ebe sawon omo orileede Naijiria wi pe ki won yee ba awon won ja lori oro awon oloselu nitori pe awon gan an lo n da orileede yi ru.

Oba Akiolu
Oba Akiolu soro yi lojo Isegun Tusde to koja yi nibi ayeye ogota odun ti arabinrin Folashade Asafa, eni to je iyawo senato to n soju ekun ila oorun nilu Ekoo nile igbimo asofin agba l’Abuja, Senato Gbenga Ashafa.

O so pe opo awon oloselu lo je pe o nibi ti won ti ma n pade lati yanju oro aarin ara won, tawon araalu tabi awon ololufee won ko si nii mo, ti won a fi maa ba ara won ja nigboro.

O ni eyin ilekun ni won ti n pari oro ju, eyi ko bo ju mu to fawon araalu lati maa ba ara won yan odi, tabi ni ara won sinu nitori ipo ose laarin awon ololufe e won.

Lara awon to wa nibi ayeye to wa ni gbongan Grand View to wa ni Magodo nilu Eko lojo naa ni Senato Bukola Saraki; Igbakeji Olori awo osise lorileede yi, Ogbeni Gbenga Makanjuola; Minisita foro ina, opopona ati ile gbigbe, Babatunde Fashola; Senato Musiliu Obanikoro atawon mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI