Aloku Navy to de iyawo e mo jenerato ti wa latimole olopaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 3, 2017

Aloku Navy to de iyawo e mo jenerato ti wa latimole olopaa

Owo olopaa ipinle Ogun ti te Ifeanyi Ajaero, eni odun metadinlogoji ti won fesun kan pe o so iyawo e, Obiageli, eni odun mejidinlogbon mo jenerato, o si ti n bebe fun oju aanu lori iwa odaran to hu naa.

Ifeanyi to lu iyawo e

Gege AWIKONKO se gbo, adugbo Ewooluwo nijoba ibile Sagamu nisele naa ti waye lojo Abameta Satide to koja yi nigba ti won so pe ale ojo Eti Fraide ni Ifeanyi ti so Obiageli mo jenerato.

Ko too dipe Ifeanyi so Obiageli mole, won loo ti koko lu daku to je pe awon araadugbo lo gba sile lowo e lale ojo Fraide naa, ti eon si yanju oro naa fun won.

Sugbon iyalenu lo je nigba ti won ri Obiageli laaro ojo Satide legbe jenerato ti oko e so mo, to si so fun won pe lati ibe loun sun mojumo.

Eyi ni won lo o bi awon araadugbo naa ninu ti won fi lo foro naa to awon olopaa ekun Sagamu leti, ti DPO Aduroja Moses si lewaju awon olopaa lati lo wo nnkan to n sele.

AWIKONKO gbo pe nigba tawon olopaa debe ti won ri Ifeanyi, ti eon si beere oro lowo e, ohun to so fun won nipe kii se oro ti olopaa le dasi nitori oro oko atiyawo ni.

Eyi ni won loo bi awon olopaa ninu ti won fi ni ko tele awon de tesan won, sugbon ohun to so fun won nipe oun ko le tele won nitori pe ise agbofinro kan naa lawon jo n se.

Obiageli, Iyawo Ifeanyi
Pelu ibinu ni won so p awon olopaa fi wo wonu moto ti won si gbe e lo si tesan won, ko too di pe won foro naa to Komisana leti, to si pase pe ki won maa gbe bo wa si Eleweran l'Abeokuta.

AWIKONKO gbo pe okan lara awon osise Navy ti won le danu lenu ise ni Ifeanyi je, won ni awon iwa ibaje to n hu lenu ise lo faa ti won fi fun nise lo gbele e.

Lara awon araadugbo naa to bakoroyin wa soro so pe kii se igba akoko re ti Ifeanyi maa lu iyawo e, Obiageli. Won ni ojoojumo lo maa n lu obinrin naa de oju iku.

Bakanna ni won so pe igba kan wa to je pe osibitu ni Obiageli laju si leyin ti oko Ifeanyi yi lu daku, to si je pe awon araadugbo naa lo sare gbe e lo si osibitu. Won ni kii gbo, kii gba ni Ifeanyi ti inu ba n bi, ko seni ti ko le soro si.

Agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa so pe bo tile je pe Komisana won, Ahmed Iliyasu ti bu enu ate lu iwa ti Ifeanyi hu naa gege bi iwa to buru jai, o ti pase pe ki eka ileese olopaa to n ri si sise eeyan nisekuse lati tesiwaju ninu ise iwadi.

Abimbola so pe nigba tawon n foro wa lenu wo, ohun to so fun won nipe oun mon on mo de iyawo oun mole lati fi daabo bo emi oun ni, nitori pe ko si nnkan ti ko le se toun ko ba gbe igbese naa.

Sugbon Iliyasu so pe awawi ti ko lese nile ni, o loun ko eeyan lati faaye gba iwa odaran bo ti wu kp kere mo nipinle Ogun nitori pe alaafia awon araalu lo je oun logun.

O wa seleri pe Ifeanyi yoo foju bale ejo laipe leyin tawon ba pari ise iwadi won. Bee lo gbawon araalu lamoran pe ki eon ma se dekun lati maa fawon to ba n huwa odaran le awon olopaa lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI