Awon araalu n binu lori ile ti Amosun tun n wo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 3, 2017

Awon araalu n binu lori ile ti Amosun tun n wo

Afaimo ki oro ile wiwo tijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun se se tun pada rawo le ma da wahala sile nitori bi awon araalu se n fi ehunu won han lori bi won se bere sii wo ile won lojiji lai fun won ni gbedeke lati ko eru won.

Nigba ti won n wo ile
Laipe yi ni ijoba ipinle Ogun bere ile wiwo naa lai fawon araalu laye lati pale eru won mo kuro ninu ile won ko too di pe won bere sii wo awon ile naa.

Bi ala loro na si n je loju awon araalu ti ijoba ipinle Ogun wo ile won nitori pe opo won ni won ko si nile lojo naa, sadede ni won ko de laaro ojo naa, ti won si bere sii wa ibi ti ile won wa kaakiri. Opo won ni won bu sekun nigba ti won rii pe ijoba ipinle Ogun ti wo ile won lai je pe won mo nipa e.

Bo tile je pe o ti le ni odun meta tijoba ipinle Ogun ti saami si pe won maa wo ile naa, sugbon ti ijoba ko gbe igbese pe awon yoo wo ile naa, tawon yen naa si n reti iwe lati odo ijoba pe ojo bayi ni won yoo bere ise ile wiwo naa, sugbon ti won ko gbo nkankan titi di ojo Aiku Sande to koja lo lohun ti Gomina Ibikunle Amosun lo sawon agbegbe naa lati lo fi to won leti pe ojo keji ni won maa bere ise ile wiwo naa, nitori naa, ki won tete ko gbogbo eru won kuro.

Bi Gomina Amosun se de awon agbegbe kan ti ise ile wiwo naa ti fee bere laaro ojo naa, to si so fun won pe ola, iyen ojo keji won n gbe katakata bo lati wa bere sii wo ile nibe, se lawon eeyan naa la enu won pe “haaa” titi ti ito fi n jabo lenu won.

Lara ile ti won wo
Bawon eeyan se n kawo lori, bee lawon kan n gbera sanle ti won n bu sekun pe ojo kan soso ti kere ju lati pale eru won mo kuro, nitori pe won ko mura sile tele lati ko eru won. Sugbon gbogbo bawon eeyan naa ti n rawo ebe pelu ekun si Gomina Amosun ni ko woju won, to kan n bu serin wipe ise ti bere nitori pe gbogbo e lawon maa se.

Lara awon toro naa kan to bakoroyin wa soro pelu ibanuje okan so pe edun okan loro naa je fawon nitori pea won ko roo ti tele pe ijoba n bo lati wa wo ile won. Won so pe ohun gbogbo lo ni ofin ti e, to si je pe bi ijoba ba fee wo ile, o ye ko ni iye ojo ti won maa fun won, iyen gbedeke ojo ti won maa gba lati fi ko eru won.

Bakanna ni won ni o lawon iwe kan wa to ye ki ijoba fun awon lati fi pe won si akiyesi, sugbon gbogbo e ni won ko ri titi di aaro ojo tise naa bere.

Lara awon adugbo toro naa kan nilu Abeokuta ni Ita-Aka, Itoku, Itoko atawon mi in bee. AWIKONKO gbo pe awon kan lagbegbe Itoku nigba tawon asoju ijoba de be lati wo ile won, ohun ti won so fun won nipe awon ko ni gba ki ijoba wo ile won nitori pe awon ti won ile won ni nnkan bi odun meji si meta seyin lawon ko tii ri owo kankan gba latodo ijoba bo tile je ori redio ati telifisan lawon ti n gbo pe ijoba ti fun won lowo, to si je pe iro ni.

Seriki Ika
Seriki Ika, Bobagunwa Gbagura, to tun je Mossobalaje tilu Egba, Oloye Fatai Abodunrin nigba toun naa n bakoroyin wa soro lori isele naa lojo Eti Fraide ose to koja, o so pe iyalenu loro naa si n je foun atawon eeyan oun ti won wo ile e lagbegbe Ita-Aka, nilu Abeokuta.

O ni iwa ti ko bojumu, ti ko si ye omoluabi ni Gomina Amosun hu nitori pe gege bi ofin, toun si ti sise leka eto oro ile ri nipinle Eko, o loo leto tijoba gbodo koko se, ko too dipe won bere igbese lati maa wo ile.

Nigba to n toka si ijoba ana, iyen isejoba Otunba Gbenga Daniel, o ni Gbenga Daniel ko too bere sii wo ile rara lo ti ko iborin miran tawon eeyan naa le gbe nitori pe aabo araalu lo se koko fun ijoba.

O ni gege bi asoju awon adugbo naa, oun ti n seto lati gbe ijoba ipinle Ogun lo sile ejo nitori pe ko seni ti ijoba Amosun fun lowo ninu awon ti won wo ile won. O ni ko seni to gba iwe pe ijoba n bo lati wa wo ile won ko too dipe won bere sii pawon eeyan naa lekun lojiji.

Ohun ti a tun ri gbo nipe opo awon molebi ti won kii gbe ilu Abeokuta, to je pe ilu Eko ni won n gbe, nigba ti won gbo ipolowo tijoba se lori redio ati telifisan pe awon ti fun won lowo gba mabinu ki won to wo ile won ni won ti bere sii de lati wa gba eto won, sugbon epe ni won n gbe Gomina Amosun se nigba ti won gbo pe iro niroyin tawon gbo lori redio.

Bee ni won so pe iro to jina si ooto niroyin tijoba so pe awon ti fun awon idile ti won ba wu oku molebi won legberun mewa naira lati fi tun oku naa sin, won ni egberun meji naira ni won fun won. Won ni kii se gbogbo won ni won fun, eleyameya ni won fi fun won lowo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI