Emi gangan ni Oba Onijaye Titun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 3, 2017

Emi gangan ni Oba Onijaye Titun

Oba Nofiu Adeyemi Otunba, Onijaye tilu Ijaye-Titun ti so pe oun ni Oba Onijaye tilu Ijaye titun nijoba ibile Abeokuta North tijoba ipinle Ogun fun lase, to si tun lowo Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo ati Oba Adedayo Olaloko Shobekun, iyen Agura tilu Gbagura ninu.

Oba Nofiu Adeyemi
 Oba Adeyemi soro yi lati fi tako oro kan to n lo kaakiri ilu wipe oun kii se Oba Onijaye, ti won si n so pe Olu Asasin ni, ati pe ona eru loun gba lati so ara oun di Oba Onijaye naa.

Bi e o ba gbagbe pe losu keta odun yi niroyin kan jade nibi tawon oloye kan ti so pe Oba Nofiu Adeyemi yee pe ara e ni Oba Onijaye ti Ijaye-Titun, wipe Olu Asasin ni won fi je, ti won si so pe oro naa ti de ile ejo, ti Alake naa si ti dasi oro naa.

Sugbon ni bayii, oro naa ti foju han gege bi awon iwe eri ti Oba Nofiu Adeyemi ko sile fawon akoroyin ni Aafin e to wa nilu Ijaye Titun lose to koja nibi ti ijoba ipinle Ogun ti bu owo luu pe oun gan an ni Oba Onijaye tilu Ijaye titun.

Kabiyesi so pe ija lo de ni orin di owe, nitori pe gbogbo awon to n so isokuso kaakiri ni won lewaju nigba tawon n seto oro oloba de yi, to si je pe awon gan an ni won lo fa oun le Alake ati Oba Agura lowo wipe oun lawon fe gege bi Oba won.

Ade Oba Onijaye
O so pe ilu meji lo parapo to di ilu Ijaye Titun, awon si ni Asasin ati Kukudi, nitori pe nigba tawon de odo Alake, ni Kabiyesi so fawon pe oun ko le fi Oba je saarin ilu mo, nitori naa ki won lo wa ilu ti won le wa lati je Oba naa si.

O tesiwaju pe Balogun Kukudi, iyen Oloye Rasaki Obe lo lewaju lati so pe ki won mu ilu Asasin gege bi ilu ti Oba maa wa ki won si yi oruko ilu naa pada si Ijaye-Titun, tawon oloye toku naa si fowo si.

Oba Onijaye tun fi kun oro e pe lakoko naa ni ileese to n ri seto idajo so pe ki won too le fun won ni iwe eri, eni ti ade ba wa lowo e ni won maa fi je oba, to si je pe oun gan lade naa wa lowo e nitori pe latigba ti won ti gbe ade naa de lodun 1832 lo ti wa nidile oun.

O ni nitori pea de naa wa nikawo oun ni ko faaye sile fenikeni lati ba oun du ipo oba naa, atipe ni gbogbo igba ti won n da ifa pe tani ipo oba to si, oun gan an ni ifa n toka si gege bi eni to leto lati je oba naa.

O so pe iyalenu lo je nigba tawon pari gbogbo eto naa, ti won fohun je Oba Onijaye. O ni ko tii ju bi osu mefa lo nibi tawon ti n se weje wemu ni ile ni enikan beere lowo oun pe toun ba waja, tani ipo oba naa kan. Ibeere yi lo bi ohun ninu, toun fi pariwo sita pe kawon araalu gba oun lowo awon to n robi roun.

O ni Alake lo bawon yanju oro naa, sugbon ko tun ju bi osu meta sigba naa ni won tun ran awon agbanipa wa ka oun mole, to si je pe Olorun lo yo oun lowo ota ibon ti won yin foun, nitori pe osu meji gbako loun fi w anile iwosan ti won gbe oun lo.

O ni leyin naa ni won tun mu oro oun lo sodo komisana olopaa ipinle Ogun nigba naa, sugbon leyin awon iwe eri toun ko sile, ni Komisana naa so pe apaayan lawon eeyan naa, nitori pe awon gan an ni odale. O so pe oun loun bawon be lojo naa nitori pe awon olopaa ti fee ti won mole ki won sig be won sile ejo.

Sugbon o so pe gege bi oba to n fe ilosiwaju to si n fe alaafia laarin ilu, oun ko mu won gege bi ota, oun tun ko won mora.

O ni orisirisi iro ni won ti pa mo oun lodo Oba Agura, eyi to si je pe Oba Agura ko beere oro lowo oun to fib ere sii gbe igbese ti ko ye ko gbe, o ni oun setan lati so gbogbo boro naa se je fun Oba Olaloko to ba ranse pe oun.

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI