Ayederu Wooli to jale ti lo fewon jura l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 18, 2017

Ayederu Wooli to jale ti lo fewon jura l’Ogun

Osu marundinlogbon gbako ni ayederu wooli, Lukman Yaya, eni odun mejilelogbon ti won lo n lo gbaju e maa lo ninu seeli, fun ti ese ti won lo se. Ojo Aje Monde to koja yi ni Adajo ileejo Majisireeti to wa ni Ota, iyen S. O. Banwo so pe oun ko nii fun ni anfaani lati san owo tabi pe ko fi nkan dipo ewon to fee lo se.

Bo tile je pe ko seni to le so pato ibi ti ayederu wooli naa n gbe, sugbon o bebe pe looto loun jebi awon esun ti won fi kan oun.

Siwaju asiko yi ni Agbejoro Chudu Gbesi ti so fun ile ejo pe ni nnkan bi aago mokanla aabo aaro ojo kejo osu keji ni ayederu wooli naa se ese naa lagbegbe Joju, ni Sango. O ni o tan Arabinrin kan, Aderibigbe Toyosi pe oun fee ran an lowo nipa isoro to ni, to si gba egberun metadinlogun ataabo lowo e, sugbon ti ko se nnkan to loun fee fowo naa se.

O tesiwaju pe ayederu wooli naa tun ji foonu towo e to egberun metalelogun to je ti obinrin naa. O lawon ese yi tapa si ofin odaran ipinle Ogun todun 2006.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI