Okunrin kan toruko e
je Solomon Emmanuel, eni odun marundinlogoji lo ti foju bale ejo majisireeti to
wa ni Ikeja lojo Aje Monde to koja yi, lori esun wipe o fipa ba omo araale e,
omodun merinla sun lojule kinni, adugbo Alonge, Oke-Odo, Agege ipinle Eko.
Emmanuel ti won ni
ise awon to n te iwe lo n se ni won ni ojo ketadinlogbon osu kerin odun yi lo
hu iwa itiju naa, to si faso boo mo naa lenu kawon araale ma baa mo nnkan to n
lo laarin won lakoko to n ko kinni abe e boo mo naa labe.
Agbejoro fawon
olopaa, Clifford Ogu nigba to n so ese Emmanuel niwaju adajo so pe se lo lo
ogbon alumokoroyi fi tan omo kekere naa wonu yara, to si so pe oun fee ran
nise. O so pe bomo naa se wole tan, lo bas are tilekun pa leyin, to si bo pata
e.
O ni nigba tiya omo
naa de lale, lo too so fun un, ti won si gba tesan olopaa lo lati lo fejo sun,
bo tile je pe iya omo naa ti yari pe afi koun gbesan, sugbon awon kan lo ni ko
lo foro naa to awon olopaa leti. O ni ese naa tapa sofin odaran ipinle Eko
todun 2015.
Bo tile je pe
Emmanuel so pe oun ko jebi pelu alaye, sugbon adajo Arabinrin Taiwo Akanni so
pe ki won si gba beeli okunrin naa pelu owo to to egberun lona oodunrun. O wa
sun ojo igbejo miran si ojo karun osu kefa odun yi.
No comments:
Post a Comment