Emir Kano fun Paseda loye tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Emir Kano fun Paseda loye tuntun

Emir tilu Kano, Sunisi Lamido Sanusi ti gboriyin fun okan lara awon oludije fun ipo Gomina ipinle Ogun lodun 2015, Otunba Olarotimi Paseda fun akitiyan e nipa mimu isokan ati alaafia wo aarin ilu paapaa orileede Naijiria.

Emir Kano, Ottunba Paseda atawon oloye nilu Kano
Emir soro yi lakoko ti Otunba Paseda atawon isongbe e sabewo karaole si aafin e to wa nilu Kano l’Ojobo Tosde ose to koja, nibe lo ti sapejuwe Paseda gege bi eni to see mu yangan lawujo, ati eni to se e fa kale gege bi asoju orileede lawon orileede kaakiri agbaye.

O so pe ti a ba n so nipa awon to n gbe asa ile e, paapaa asa ati ise Yoruba laruge, Otunba Paseda je okan pataki ninu won, eni to si yye lati fi se oju orileede lagbaye, to si je pea won ipa to ti ko ko see fowo ro seyin.

Lakoko abewo naa lawon eya Awusa (Hausa) to n gbe ipinle Ogun ti fi Otunba Paseda han Emir Sanusi gege bi Garkuwan Hausawan nipinle Ogun, iyen oye ti won fun gege bi eni to nife awon eya to ku, paapaa awon eya Awusa.

Emir Sanusi so pe looto ni won ko fi ojusaaju fun Otunba Paseda loye Garkuwan nitori pe iroyin bo se n fowosowopo pelu awon eya Awusa nipinle Ogun ko see gboju fo da, o si ye kawon da a lola repete.

Otunba Paseda ati Emir Kano
O loun ko kabamo pe oun fi oye naa ta Paseda to je omo bibi ilu Ijebu naa lore, eni to n fi iwa omoluabi e han sawon eeyan, paapaa awon araalu e, to fi mo awon eya to ku lorileede yi, ati nile Adulawo, iyen Afrika.

Emir Kano wa lo akoko naa lati gba Otunba Paseda lamoran wipe ko rii daju wipe o n yoju silu Kano lakoko to ba, paapaa nigba ti won ba n se ipade awon oloye, nitori pe oye naa je okan pataki lara awon oye nile Awusa, ko si ri daju wipe ko si ipo oye naa lo.

Otunba Paseda wa dupe gidigidi lowo Emir tilu Kano, awon oloye atawon agbaagba nilu Kano, o si seleri fun won pe oun yoo sa gbogbo agbara ati ipa oun lati rii pe alaafia ati isokan n joba laarin awon eya Yoruba ati Awusa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI