Nitori gbese; Yetunde para e ni Somolu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Nitori gbese; Yetunde para e ni Somolu

Gbajumo dirun-dirun (hairdresser) kan ladugbo Onabola Owotutu ni Somolu nipinle Eko, yetunde Oladipupo topo mo si Iyabo la gbo pe o ti gbe oogun apefon (insecticide) mu nitori gbese ti won so pe o je enikan.

Gege bi AWIKONKO se gbo, nirole ojo Eti Fraide to koja yi won ni ore e kan wa ki, bo tile je pe ko se ni to le so pato idi tiyen fi wa ki, sugbon ohun ti a gbo nipe, ko pe ti ore e yi lo, la gbo pe Yetunde gbe Yetunde gbe oogun apefon to ti ra lati aaro mu.

Awon araadugbo ti won ri nibi to ti n lo inu mole ni won sare gbee lo si osibitu kan ni Gbagada lati doola emi e, sugbon nigba ti won fi maa gbe sori beedi, o ti dake, elemin ti gba a.

Yetunde, iya olomo merin la gbo pe o je omo bibi Ijebu-Igbo nipinle Ogun lo gba owo to je ogoje ataabo naira (N150,000) nile ifowopamo microfinance tawon to gba owo lowo e si ti n daamu e pe ko tete wa a san owo to je won.

Lara awon to ba AWIKONKO soro nipa omobinrin naa, won ni Abuja loko e ti n sise, to si je pe eekookan lo maa n wale lati yoju si won, won loko naa ko bikita lati maa se ojuse e gege bi baba ati oko, eyi lo fa ti won so pe Yetunde fi lo o gba owo naa, ko si le maa fi ri nnkan ta.

Sugbon se ni won so pe, oja to fi owo naa ra ko ya, bukata omo merin lo si je ko je pe owo to n pa, bukata ounje ati owo ileewe awon omo naa lo fi n gbo, eyi ti ko fun ni anfaani lati maa ri owo dapada fawon banki to ya owo naa lowo won.

Won ni nigba ti wahala tawon osise banki to ti lo yawo naa n fun lo fi woo pe koun gbemi ara oun ko too pe ju, ki oju ma baa tii ladugbo.

Enikan lara awon araadugbo to tun ba AWIKONKO soro so pe awon ore e meji ti waa ki, to si sin won lo ni nnkan bi aago meje irole, sugbon nigba to n pada bo lo ya sinu soobu kan to wa niwaju ita ile to n gbe, to sir a oogun apefon.

O ni leyin to ra oogun apefon naa tan, lo beere lowo eni to ra a lowo pe ko foun ni ora (nylon), sugbon tiyen so pe ko si. Inu iro aso to wo lo so pe o yi kini naa mo. O nib o se n gun oke ile to n gbe lati maa wonu yara lo, lo mu oogun apefon naa tan bamubamu.

Loju ese lo ti bere sii je irora, to si n lo inu mole, ko too sare pe omo e, omodun marun to wa nitori lati wa ran an lowo, ko si baa pe awon agba to wa layika. Ileele nibi to ti n yi kiri ni won ti ri pelu ike apefon to mu, nibe lawon eeyan ti pariwo sit ape ki won gba awon.

Lesekese ni won ti seto lati gbe e lo si osibitu boya won si le ra emi e pada, sugbon won ni epa ko boro mo nigba ti won fi maa de osibitu jenera to wa lagbegbe Gbagada nitori ti won so pe dokita marun ni won ni won lakaka lati du emi e.

Aaro ojo Abameta Satide ni won loo dake si osibitu naa nitori ti won so pe kini to mu ti je ifun e koja aye ki won too gbe debe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI